Akinyele Ibadan land crisis: Àwọn olùgbé Akinyele fí ẹ̀sùn ilẹ̀ gbígbà kan ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, ìjọba Makinde ti fèsì padà

Iwode

Awọn olugbe Akinyẹle fi ẹsun ilẹ gbigba lọna aitọ kan ijọba ipinlẹ Ọyọ, ijọba ipinlẹ Ọyọ fesi

Awọn olugbe ileto Olorisa-Oko to n bẹ ni ijọba ibilẹ Akinyẹle ipinlẹ Ọyọ ti ṣe ifẹhonuhan lọ si ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ nilu ni agbegbe Agodi ilu Ibadan l'Ọjọbọ.

Wọn ni awọn ṣe eyi lati parọwa si gomina Ṣeyi Makinde pe ki o wọgile erongba ati gba ọpọlọpọ saare ilẹ lati fi da "Ilu Tuntun" silẹ ni agbegbe naa.

Awọn olufẹhonuhan naa fi igbe ta wi pe o kere tan, awọn eeyan ti o to bi i ẹgbẹrun lọna aadọta ni awọn ileto mẹtalelogun ọtọọtẹ bẹrẹ lati Olorisa Oko si Onkoko ni yoo di alaini ile lori laipé.

Iyẹn bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ba tẹsiwaju ninu ẹrongba rẹ lati gba heka ilẹ ẹgbẹrun kan le lẹẹdẹgbẹta.

Àkọlé fídíò,

Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji

Wọn fi kun ọrọ wọn wi pe ọpọlọpọ ilẹ ni awọn ijọba to ti wa tẹlẹri gba fun akanṣe iṣẹ ni agbegbe Akinyẹle, bẹrẹ lati ibudokọ, ọna olobiripo, ọpọpọna ọkọ ojurin, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Wọn salaye wi pe iṣoro ti o pọ yoo koju awọn olugbe agbegbe naa bi ijọba ba tẹsiwaju lati maa gba ilẹ wọn fun akanṣe iṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Test your Yoruba language skill: Wá ká jọ sọ Yorùbá...

Igbakeji alaga ọkan lara awọn ileto ti ọrọ naa kan, Abeowu Akuro, Arabinrin Mary Adeniji, ṣe alaye pe ohun to fi idi ẹ mulẹ wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ gba ilẹ wọn, ni patako ajuwe to n ṣe afihan iwọn ilẹ ti ijọba ti gbẹsẹ le ni agbegbe naa.

Àkọlé fídíò,

Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Olugbe mii to ba awọn oniroyin sọrọ, Arakunrin Seriki Mr Seriki Kazeem ṣe alaye wi pe oun ko tako iṣẹ itẹsiwaju, ṣugbọn "kini eto ti ijọba ni fun awọn eeyan ti yoo padanu ilẹ ati ile wọn sọwọ akanṣe iṣẹ ti ijọba fẹ ṣe"

Àkọlé fídíò,

Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

Kini ijọba ipinlẹ Oyo sọ lori ọrọ yii?

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fesi lori ẹsun naa ninu atẹjade ti wọn fi lede gbatọwọ akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ Ọyọ,

Àkọlé fídíò,

Ọlatunji, akẹ́kọ̀ọ́gboyè 'graduate' tó ń ta àkàrà 'Ó ta lẹ́nu' nílùú Osogbo

Arakunrin Taiwọ Adisa tọka rẹ wi pe Gomina Ṣeyi Makinde ni ijọba n gba awọn ilẹ naa lati ṣe idasilẹ awọn ileto to bojumu ti wọn pe ni "Ilu Tuntun" ti yoo jẹ apẹrẹ ayika to leto.

Àkọlé fídíò,

Ohun ti Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sátánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́

Atẹjade naa tẹsiwaju pe jakejado ipinlẹ Ọyọ ni agbekalẹ naa yoo ti waye, ṣugbọn ijọba ibilẹ Akinyẹle ni wọn ti bẹrẹ.

Makinde fi kun ọrọ rẹ wi pe ero ti eto rere ni oun ni fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, yoo si rọrun ti wọn ba fi ọwọ sowọpọ pẹlu ijọba.

Àkọlé fídíò,

Ilé wó lu Bisi, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kú, wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ tó ń jẹrà, inú ìrora ló wà ṣùgbọ́n