FRSC: Bó o bá fí ''Earpiece" sétí lásìkò tó ń wakọ̀, ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà ni

Oríṣun àwòrán, Roadsafety
Àjọ tó n mójú tó ààbò lójú pópó (FRSC) ti kéde pé ẹ̀sẹ̀ sí òfin ni kí ó máa wakọ̀ kí ó fi agbọ̀rọ̀sọ (Earpiece) sétí irú èyí yóò wù kí ó jẹ́.
Àjọ FRSC tún fi ku bákan náà pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wakọ̀ tó sì ń waks, yálà ó lo Airpiece, Airpod, Earpod tabí irú èyikéyì irú rẹ̀ ń fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà runmú ni.
- Ògo ilé wá wọlẹ̀ lójijì! àwọn darandaran ajínigbé pa abúrò mí! - Ọmọyẹle Ṣowore
- Ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram 6,000 ti jọ́wọ̀ ara wọn fún ìjọba Naijiria
- Àwọn jàndùkú tún ṣọṣẹ́ ní Zamfara, wọ́n pa ọlọ́pàá kan àti olórí fijilanté
- Ẹni ọdún 19 dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fẹ̀sùn kan JAMB pé èsì ìdánwò méjì ni wọ́n fún òun
Graphology: Wo àǹfààní márùn-ún tó wá nínú ìmọ̀ nípa ‘Handwriting’ rẹ
Bisi Kazeem tó jẹ́ adarí ìlanilọ́yẹ fún àjọ náà ló fi ìdí èyí múlẹ̀ lásìkò tó n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé, gbogbo ọkàn ènìyàn lo gọ̀dọ̀ wà níbi ọkọ̀ tí ó n wà kí aabò tó yẹ lé wà fún gbogbo ẹni tó n lo ojú pópó.
Ó ní ẹ̀ṣl sí òfin ni láti máa gba ìpè lásìkò tí ènìyàn bá ń wa mótò, nítorí náà kò sí ààyè láti má ṣe nǹkan mííràn, òfin ìrìnà ni láti ọdún 2012.
Gẹ́gẹ́ bí òfin Reg 166 (1) ṣe sọ, ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin ni láti máá fi agbọ̀rọ̀sọ tàbi ohunkóhun gba ìpè lásìkò tí ènìyàn bá ń wakọ̀.
" Gbogbo nǹkan ti yóò bá mú ọkàn rl kúrò níbi mótò tí òun wà, ní kí ó sá fún, nígbà mííràn tí a bá ń ṣe ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ ìta gbàngba , a máá n sọ fún àwọn ènìyàn kí wọ́n má bá àwọn èrò inú ọkọ̀ wọn sọ̀rọ̀ nítorí ó le fa wàhálà.