Dele Ewe US Fraud: Ọmọ Nàíjíríà bíi Hushpuppi, Dele Ewe tún rí ẹ̀wọ̀n oṣù 30 he ní Amerika fún ẹ̀sùn 419

Bamidele Muraina

Oríṣun àwòrán, other

Ọmọ Naijiria miran to tun gbajugbaja bii Hushpuppi lori Instagram, Bamidele Maraina ti ọpọ eniyan mọ si Dele Ewe ti ri ẹwọn ọṣu aadọrin lorilẹede Amerika.

Dele Ewe to wa lati ilu Osogbo, nipinlẹ Osun ati amugbalẹgbẹ rẹ Gabriel Kalenbo lati orilẹede Zambia ni ijọba orilẹede Amẹrika ni wọn jẹbi ẹsun iwa gbajuẹ.

Ẹsun ti ijọba orilẹede Amẹrika fi kan Hushpuppi ni pe o lu ọwọ iranwọ covid-19 ni ponpo nipa lilọ ẹrọ ayelujara.

Ninu ọrọ ti adajọ sọ ni Amerika, Dele Ewe ati ọrẹ rẹ ti wọn jọ hu iwa ibi yii, Gabriel Kalenbo lati orilẹede Zambia ni wọn ji owo iranwọ ti ijọba fẹ fi ran awọn oṣiṣẹ ati ẹbi lọwọ lasiko ajakalẹ arun Covid-19 ti iya ati iṣẹ n ba awọn eniyan finra.

Dele ati ọrẹ rẹ ni wọn ja ẹka ileese to n risi igbanisiṣẹ ni ilu Washington, Employment Security Department of Washington State ("ESD-WA"), nigba fi fi ọna ẹburu gba eto adojutofo (insurance) awọn oṣiṣẹ, ti wọn ko si jẹ ki awọn to ni ẹtọ si owo naa ri gba.

Ileẹjọ ni Dele ri ọna gba owo awọn eniyan lori ẹrọ ayelujara naa nipa jiji orukọ wọn ati ohun idanimọ awọn olugbe ilu Washington, ti wọn si gbe kalẹ gẹgẹ bi orukọ wọn lati fi gba owo labẹ eto iranwọ ijọba apapọ lati doju ti iya ati iṣẹ lasiko ipenija aarun Covid-19.

O kere tan araalu to le ni aadọta ni Dele ati ọrẹ rẹ to wa ni orilẹede Gambia lu ni jibiti ni iye owo to le ni $280,000, ti ijọba fun awọn ti ko ni iṣẹ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Ko tan si bẹ o, olubaṣiṣẹpọ Dele naa ran awọn eniyan lọ si orilẹede Amerika ni agbegbe Georgia lati lọ ṣi awọn ileeṣẹ, ti wọn si tun ṣi apo ifowopamọsi ni awọn banki to wa nibẹ.

Lẹyin ti wọn gba awọn owo adojuti osi yii tan ni orukọ awọn araalu, wọn gba owo naa jade pẹlu kaadi ATM wọn ati awọn nkan ti wọn ra, ki ọwọ to tẹ wọn.

Ninu idajọ naa, Adajọ paṣẹ pe ki Dele Ewe san iye owo to to $561,125.62 gẹgẹ bi owo gba ma binu ti wọn da pada fun ẹṣẹ iwa jibiti ti o hu.

Bakan naa ni ọrẹ rẹ, Kalembo to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa yoo san iye owo ilẹ okeere to to $298,008.71 pada fun awọn ẹni to lu ni jibiti, ti yoo si fi ẹwọn oṣu aadọta jura ni orilẹede Amẹrika.

Laipẹ yii ni ẹka idajọ orilẹede Amẹrika fi ẹsun kan ọmọ Naijiria Ramomi Abass, ti ọpọ eniyan mọ si Hushpuppi pe o lu jibiti ori ayelujara ti owo rẹ to miliọnu kan ati ẹgb€run lọna ọgọrun Dọla.

Bakan naa ni Hushpuppi ti n ka awọn eeyan ti wọn dijọ lọwọ ninu ẹsun lilu jibiti naa, ninu eyi ta ti ri ọga ọlọpaa kan nilu Eko, Abba Kyari.