EFCC Lekki Yahoo Boys: Tí ẹ bá ń wá ibi tí àwọn ọmọ Yahoo, 419 pọ̀ sí nípinlẹ̀ Eko, Lekki ní!

Yahoo

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti tọka si agbegbe Lekki nipinlẹ Eko gẹgẹ bi agbegbe ti awọn ọmọ Yahoo pọsi julọ nipinlẹ Eko.

Ni oju opo ikansiraẹni Facebook Ajọ EFCC ni wọn fi lede si oju opo ikansiraẹni Facebook wọn pẹlu akọle pe Lekki ti da ibujoko awọn gbajuẹ bayii, 'Lekki now hotbed of cybercrime - EFCC'.

Atẹjade ti EFCC gbe jade fihan pe awọn afurasi ọmọ yahoo mejileniirinwo lọ wa ni panpẹ, ti ọwọ awọn tẹ laarin oṣu mẹta.

''Awọn agbegbe ti awọn ọmọ Yahoo tun pọsi ni Ajah, Badore, Victoria Garden City, Sangotedo ati Oniru ni agbegbe Lekki.''

Bakan naa ni EFCC ni awọn ọdọ ti ko ju ẹni ọdun marunlelogun si ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ni awọn to n hu iwa ibajẹ lawujọ yii.

''Ninu awọn ti a ri ko laipẹ yii, aadọrin ninu wọn ni wọn n gbe ni agbegbe Lekki''

Iwadii fihan wi pe ohun ti awọn ọmọ Yahoo yii n ṣe ni lati lo gbajuẹ fun ẹnikẹni to ba bọ ọwọ wọn nipa ọrọ ifẹ tabi lọkọ-laya de, eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni ''Dating Scam/Online Dating Scam/Romance Scam.''

Ajọ EFCC ni ida mẹrinlelọgọta awọn ti wọn mu ni wọn n ṣe iru nkan bayii.

Oríṣun àwòrán, EFCC

Eleyii to tẹle ni ki wọn ma a lo alarinna, eyi ti wọn n pe ni "Middle Man Scam" ati "Picking", eleyii to jẹ ida mẹjọ si meje awọn to n ṣe iṣẹ Yahoo ninu awọn ti ọwọ tẹ.

Awọn to n parọ lọkọ-laya abi ti wọn n lu eniyan ni jibiti lori ọrọ ifẹ ni wọn n gba owo to lẹ ni ẹgbẹgbẹrun miliọnu naira lọwọ awọn ololufẹ wọn, to fi mọ owo ilẹ okeere.

Ko tan si bẹ, awọn gbajuẹ yii tun n yi iwe, ti wọn si n gba iwe ẹri awọn eniyan, wọn a ji ATM card, wọn tun n gburo gba owo ile, ẹyawo naa, jiji e-mail awọn eniyan ati bẹẹ bẹẹ lọ.