Guinea Coup: Àwọn ọmọogun orílẹ̀èdè Guinea ti gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ Alpha Conde

Oríṣun àwòrán, AFP
Iroyin to n jade lati orilẹede Guinea n fi lede pe awọn ọmọogun orilẹede naa n gbiyanju lati gbakoso iṣejọba lorilẹede naa.
Iroyin ni awọn ẹṣọ oloogun naa ti fi panpẹ mu aarẹ orilẹede Guinea, Alpha Conde.
Ni bayii, ikọ ọmọogun orilẹede naa ti bọ sọri ẹrọ tẹlifisan lati fi to awọn araalu leti wi pe awọn ti gba ijọba orilẹede naa.
- Kà nípa ìtàn okùnrin tí obìnrin 200 gún lọ́bẹ pa, tí wọ́n sì tún gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ sọnù
- Buhari, ọgá ilééṣẹ́ aṣọ́bodè rẹ́ kò mọ̀ iṣẹ́, yọ́ọ́ kúrò nípò-Sẹ́nẹ́tọ̀ Francis Fadahunsi
- Àwọn aláìní nǹkan ṣe lo n pè fún ìyapa Nàìjíríà- Gómìnà Oyetola
- Kí ló mú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìlera JOHESU fún ìjọba Nàìjíríà ní gbèdéke ọlọ́jọ́ 15 ṣáájú ìyanṣẹ́lódì?
Bakan naa ni wọn fikun pe awọn olori jankan-jankan lorilẹede naa ti wa ni abẹ panpẹ awọn ẹṣọ alaabo orilẹede naa.
Wọn fikun pe alaafia ni aarẹ Alpha Conde wa, ni abẹ isakoso ati aabo awọn ologun.
Oríṣun àwòrán, AFP
Saaju asiko yii ni iro ibọn ti n dun lakọ lakọ nibẹ, ki iroyin labẹle to gbe e pe alaafia ni aarẹ Conde wa, ti awọn ẹṣọ alaabo to wa ni ile aarẹ ṣi n da abo bo o.
Amọ ileeṣẹ iroyin lorilẹede naa, RTG TV ko i tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa, ti wọn ṣi n ṣe iṣẹ wọn lọ bi ẹni pe ko si nkankan to n ṣẹlẹ nibẹ.
Idibo sipo aarẹ Alpha Conde fun saa kẹta ni Oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja lo mu rogbodiyan dani, ti awọn eniyan si bọ sita lati fi ẹhọnu naa lori esi idibo to gbe e wọlẹ fun saa kẹta.
Eyi lo mu ki awọn ologun ilẹ naa kọkọ doju ija kọ awọn ẹgbẹ alatako, ko to di pe iṣẹlẹ ifipagba ijọba waye lorilẹede naa.