BBNaija: Ẹ wo àwọn tó kọjú ìjà sí ara wọn nínú ilé Big Brother Naija

BBNaija

Oríṣun àwòrán, Others

Ija laarin awọn olugbe ile Big Brother Naija ko jẹ tuntun mọ fun awọn eniyan ni saa ti ''Shine ya Eye'', amọ Queen ati pẹrẹ lo gbena woju ara wọn ni ọpin oṣẹ.

Eleyii ko ṣẹyin bi Angel ati Boma ṣe woju ara wọn ti ọrọ si di yanpọn-yanrin.

Oríṣun àwòrán, Others

Arabinrin Queen ko gbe ni tutu rara fun Pere lẹyin to lọ ba awn to wa ni ile idana wi pe oun wa towẹli ati aṣo irọri oun.

Eyi dabi ẹni pe Pere n naka abuku si Whitemoney, eleyii to bi Queen ninu to si bẹrẹ si ni gbe ija r, ki wọn to bẹrẹ si ni taun si ara wọn.

Ọrọ yii da wahala to jẹ pe, Queen kesi Pere wi pe ko dakẹ ẹnu rẹ ko si ma sọ ọrọ kugbakugbe si oun.

Ati wi pe ile Big Brother Naija kii ṣe ile Pere, ko ye ṣe bi ẹni pe oun dara ju gbogbo eniyan lọ.

Queen ni to ba buru ju fun Pere, ko jade kuro ninu ile, to ba ti mọ wi pe oun ko le e bọwọ fun ẹlomiran ninu ile.

Amọ niṣe ni Pere n ṣin Queen jẹ, to si ṣe họbi rẹ ninu ile pẹlu bi o ṣe n binu.

Oríṣun àwòrán, Big Brother Naija

''Whitemoney pe Pere pe oun ko fẹran iwa aibikita to n hu si oun ninu ile''

Ko tan sibẹ, lẹyin naa ni Queen ati Angel bẹrẹ si ni sọrọ Pere pẹlu bi o ṣe ma n ṣe si Whitemoney ninu ile Big Brother Naija.

Wọn gbogbo igbiyanju Whitemoney lati tẹ Pere lọrun, lo jasi pabo nitori iwa aibikita ti pere ma n hu si.

Lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye ni Whitemoney pe Boma, Saga ati Pere fun ara rẹ si inu yara ti wọn n pe ni Games Room to si sọ pe oun ko fẹran iru iwa ti Pere ma n hu si oun.

Whitemoney ni Pere ma n wo oun bi ẹni pe Olorun kọ lo ṣeda oun, amọ oun ma n fi oju fo.

O kilọ fun pe ko ye yẹyẹ oun ni oju gbogbo eniyan mọ, nitori ọmọ Naijiria ni oun, ti oun si fẹran irẹlẹ ati ibọwọ fun ara ẹni.

Awọn ọkunrin naa gbiyanju lati pari aawọ naa bi o tilẹ jẹpe ko si ẹni to bẹ ẹnikeji rẹ.