Yoruba Nation: Agbègbè Benin ni mo wà lásìkò tí wọ́n mú Sunday Igboho, kíá sì ni a gbé ìgbésẹ̀-Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye
Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akointoye ní kò ṣeéṣe fún àwọn olùpè fún Yorùbá Nation láti kó gbogbo ènìyàn ní túlásì pé kí wọ́n lọ fún Yorùbá Nation bíkò se àwọn tó bá wù.
Lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú BBC ní Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye tó n ṣe agbátẹrù fún gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá tó ń pè fún òmìnira ara ilẹ̀ Yorùba ti ṣàlàyé pé, agbègbè Benin Republic ni òun wà nígbà ti wan mú Sunday Igboho
Akintoye ni, ni kété ti wọ́n mu Sunday Igboho ni ìròyìn ti dé ibi tí òun wà bẹ́ẹ̀ náà si ni wọ́n gbé ìgbésẹ̀ nípa pípe àwọn agbẹjọ́rò tó n dántọ́
Akintoye ni ìgbésẹ̀ tí àwọn gbé yìí ni kò jẹ́ kí wọ́n rí Sunday Igboho gbe padà sí Nàìjíríà.
"Lẹ́yìn tí àwọn agbẹjọrò ṣe ṣe ojú wọn tan ni ìjọba Nàìjíríà kọ àwọn ẹ̀sùn oníruurú ìdí tó fi gbọdọ̀ pàdà sí Nàìjíríà, sùgbọ́n àwọn adájọ Benin sọ pe gbogbo èsun tí wọ́n fi kàn kò níṣe pẹ̀lú dídá padà sí Nàìjíríà.
- Eéwo ni mo kọ́kọ́ pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo ní- Adebukola Adediran
- Wo àwọn Fasiti Nàìjíríà tó gbégbá orókè lágbàyé
- Olu Jacobs àti Joke Silva yan orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ wo ohun tó mú ìgbéyàwó wọn dúró
- Wo nkan márùn-ún tí o kò mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láàrin tọkọ-taya
- Ẹ̀yin Òbí, ẹ fi ọmọbìnrin yin sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ tó wù wọ́n- Deborah tó ń fi ìlú bàtá àti gángan dárà
Mo gbọ́ pé àwọn Yorùbá wà lára àwọn tó n gbógun ti Sunday Igboho- Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye
Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ ko fi bẹ́ẹ̀ dá dáada, síbẹ̀ ó wa ni alafia, jíjòkó tó n jòkó sójú kan wà lára nǹkan to da àìsàn si lára, sùgban ko dáa dùbúlẹ̀.
Ìròyìn tó n lọ ká ni pé, àwọn ọmọ Yorùbá kan ló n kún ìjọba Nàìjíríà lọ́wọ́ láti gbógun ti Sunday Igboho, sùgbọ́n láílái ni ọ̀dàlẹ̀ máa ń wa láwujọ.
Akintoye dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Benin nítorí pé wọ́n ń tẹ̀lé òfin, èyí sì ló jẹ́ kí nǹkan rọ̀rùn fún Sunday Igboho titi di àsìkò yìí.