Niger kidnap: Àwọn jàndùkú ajínigbé gbé Emir lọ ní ààfin Borgu

Oríṣun àwòrán, Emir Borgu
Ọrọ di bo o lọ ya fún mi ní ààfin Emir Borgu nipinlẹ Niger nigba ti awọn ajinigbe pawó aafin naa nibi ti wọn ti gbe Emir lọ.Awon janduku agbebọn ọhún ni a gbọ pe wọn yabo ilu Emir naa, Dodo ti Wawa, Ọmọwe Mahmud Ahmed ti wọn gbe e lọ.Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe alupupu ti ọpọ mọ sí ọkada lawọn agbebọn náà gun wa.
- Ọmọ ilú Osogbo bíi Hushpuppi, Dele Ewe rí ẹ̀wọ̀n oṣù 30 he ní Amerika fún ẹ̀sùn 419
- Whitemoney, Queen, Pere, Angel, Boma kọjú ìjà sí ara wọn nínú ilé Big Brother Naija
- Yoruba Nation kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Naijiria, ìlànà àtúntò ni - Deji ti Akure
- Ẹni ọdún 19 dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fẹ̀sùn kan JAMB pé èsì ìdánwò méjì ni wọ́n fún òun
Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation
O ni lẹsẹ kẹsẹ ni wọn da ibọn bo ilẹ lati d'ẹru ba ẹnikẹni tó fẹ di wọn lọwọ iṣẹ ibi ti wọn fẹ ṣe.6Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, Wasiu Abiodun fìdí iṣẹlẹ ọhún múlẹ fawọn akọroyin.Abiodun ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti bẹ sinu igbó lati doola Emir Borgu lọwọ awọn janduku agbebọn náà .Emir ti wọn gbe lọ yii ni a gbọ pe o jẹ Dodo Wawa ẹlẹẹkẹrindinlogun, o sí ti wa lori oye fún ọdun mejila.