Ẹgba àtorì méjìlá ni Adájọ́ ni kí wọ́n tò sí ìdí Marvellous Farina tó jí irin iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná lásikò tó ń ṣe lébìrá níbẹ̀

Atori

Oríṣun àwòrán, others

Ileẹjọ giga kan ni Zuba nilu Abuja ti dajọ ijiya ẹgba mejila fun lebira kan Marvellous Farina to lọ jin irinsẹ ipese ina mọnamọna.

Ẹni ọdun mọkanlelogun yi ni Adajọ Gambo Garba gbe idajọ yi kalẹ le lori to si ni ko san owo itanran ẹgbẹrun mẹwaa dipo ko ṣe ẹwọn oṣu mẹfa lori ẹsun pe o fọle onile.

Marvellous ni oun jẹbi ẹsun naa to si beere ki adajọ foju aanu wo o.

Lẹyin ti adajọ gbọ́ ẹbẹ rẹ tan, o tun pasẹ ko san ẹgbẹrun lọna igba Naira gẹgẹ bi gba mabinu fun ẹni to fi ẹsun kan an.

Saaju ni agbẹjọro awọn to mẹjọ wa, Chinedu Ogada ti sọ fun ile ẹjọ pe Adene Ojo ati Adene Olu ti wọn n gbe ni adugbo Anagada Green Garden Area Abuja ni wọn fẹjọ sun.

Àkọlé fídíò,

Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

O ni ni agọ ọlọpaa to wa ni Zuba ni wọn mu ẹjọ naa lọ lọjọ Kẹta, oṣu Kẹjọ.

Ọgada sọ pe ọdaran Marvellous ati eeyan kan Israel Ibrahim jijọ fọ lẹkun wọ inu ile awọn to mẹjọ wa ti wọn si jin irinsẹ ina mọnamọna ti iye owo rẹ to ẹgbẹrun lọna igba Naira.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

O tẹsiwaju pe lẹyin iwadii awọn afurasi naa jẹwọ fun ọlọpaa pe lootọ lawọn fọle sugbọn gbogbo akitiyan lati ri awọn nkan ti wọn ji gbe gba pada lọwọ wọn ja si pabo.

Agbẹjọro ni ẹṣẹ ti wọn ṣẹ tapa si ofin orileede Naijiria to de iwa ọdaran.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú