Cow meat taboo: Bí jíjẹ ẹran Màálù ṣe d'èèwọ̀ nílùú wá torí ohun táwọn darandaran ṣe rèé

Suya

Ẹran Suya kii ṣe aimọ ni Naijiria, ẹran maalu sì ni wọn fi ń ṣeé. Amọ títa ati jíjẹ ẹran naa ti di eewọ gbaa ni ilu Uwheru ni ìhà Gúúsù Naijiria.

Eyi jẹ ní ibamu pẹlu òfin kan to tí bẹ̀rẹ̀ lati ọjọ kejilelogun oṣù keji ọdun 2020.

Ọrọ naa ko rẹrin rara ni ilu Uwheru ipinle Delta óò si le dede maa mu ẹran Suya, Kilishi jẹ tabi fi maalu se ọbẹ̀ rara.

Àwọn olori ìlú náà ni àwọn gbe ofin kalẹ nitori ìkọlù to waye laarin awọn agbẹ àtàwọn darandaran.

"Ìdí ni wipe niṣe lọmọ èèyàn bẹ̀rẹ̀ si ni kú nitori maalu". Eyi ni ọjọgbọn Patrick Muoboghare sọ fun BBC.

Lasiko ti o n ba BBC sọ̀rọ̀, Ojogbon Patrick ni òfin ti wọn ṣe lori jijẹ ẹran maalu kii ṣe pe wọn kan ṣeé lasan sugbọn "bẹẹ ni yoo wa titi lai lai".

Àkọlé fídíò,

Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

BBC lọ s'ilu naa lati mọ bi awọn araalu ṣe n tẹle ofin naa si nígbà naa o ti pé ọdún kan ati oṣu mẹfa ti wọn pàṣẹ "ma ta, ma jẹ ẹran maalu.

Ṣe araalu n tẹle ofin "ma jẹ maalu"?

"Iroyin to n wá si mi leti ni pe awọn kan nilu n rún ofin amọ ni temi ati ile mi, a o ni jẹ ẹran maalu".

Dokita Ochuko Nafoba to jẹ ọmọ ilu ni lootọ àwọn kan n ṣe owo maalu ninu ilu amọ ọpọlọpọ sì wa tó n tẹle ofin naa gidi gan.

Lori idi ti awọn kan ko ṣe tẹle ofin naa,

Ochuko ni tìtorí ẹsin Kristẹni ni àtàwọn nkan mii lo faa.

"Ìṣòro tó wà ní ìlú Uwheru ni torí ẹsin Kristẹni àtàwọn nkan mii, awọn èèyàn ò bọ̀wọ̀ fún eewọ bo ṣe yẹ ki wọn ṣe.

Nígbà tí wọ́n koko gbé òfin náà kalẹ, àwọn eeyan ṣe ìnáwó isinku, igbeyawo, wọn kò si pa maalu rara, àwọn ẹran míì ni wọn lọ àti ẹja torí ìlú tó ní ọ̀pọ̀ ẹja ni Uwheru.

Laipe yii ni ẹgbẹ́ àwọn darandaran sọ pé owó maalu kan leè to milionu méjì bayii torí òfin àwọn tó fagile dída ẹran jẹ ọkọ làwọn ipinle Naijiria kọọkan.