Dudu Heritage: Ikú Ola Ibironke bá wa lójijì nítorí pé onínúure ni olówó orí Bimbo Oshin sí gbogbo wa- Rose Odika

Jaye Kuti ati Rose Odika

Ọ̀pọ̀ awọn eeyan ni wọn ṣi n banujẹ lori iku Ola Ibironke Dudu Heritage.Ta ni Ola Ibironke, ọkọ Bimbo Oshin to dólògbé?

Awọn eeyan lorisirisi n jade sọrọ nipa bi o ṣe ṣelẹ ati ohun to fi ka wọn laya.

Gbajugbaja oṣere ni, Jaiye Kuti to jẹ ọrẹ timọtimọ fun aya oloogbe naa ni pe oloogbe naa ko ṣaisan kankan rara.

O ni ko si ẹni ti kò ní lọ ṣugbon ọjọ oni kaluku lo yato si ara wọn lati dero ọrun.

Igba ti iṣẹlẹ yii sẹlẹ wọn kò mọ bí wọn ṣe fẹ pe Bimbo Oshin leyin to mu kí wọn pe òun fun iṣẹlẹ buruku naa.

''Emi gan an ti wọn pe ti di jatijati lẹyin ti won pe mi fun iroyin buruku naa".

Àkọlé fídíò,

Ijesha tennager police death: O yẹ kí wọ́n máa yẹ ọpọlọ ọlapàá wò kí wọ́n tó gbà wọn síṣẹ

Honorebu Olawale Abdul Majeed - Igbakeji olori oloṣelu Seyi Makinde ni ipinlẹ Oyonaa ba BBC Yoruba sọrọ nipa oloogbe pe o dabi ẹgbọn ti mo mọ lati okeere ni ti wọn jẹ eeyan daadaa.

O ni: Mo ti maa ń gbọ oruko lati okeere ni ẹyin igba ti wọn ku ni mo mọ wi pe awọn ni wọn jẹ Dudu Heritage.

Àkọlé fídíò,

Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

Oladapo Olaide okan lara awon omo ẹgbẹ ibadan golf club sọrọ nipa oloogbe ilẹ kun.

O sọ pé oloogbe pe òun ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ leyii to jẹ pe wọn ko pe ara wọn ni iru asiko bẹ ríi.

O pe lati fi ẹjọ nnkan to sẹlẹ ní golf club sùn òun leyii tó jẹ pé enikan níbi iṣẹ ni ó ṣẹ oloogbe ṣugbon òun àti àwọn ọmọ ẹgbẹ kọọkan bẹ́ẹ̀ tí ọrọ náà sí pada yanju.

Àkọlé fídíò,

Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Nibi tí wọn gbe gbero lati pe foonu ẹni tó ṣẹ oloogbe ki wọn le fi tó leti pé ija ti pari, sa deede lawọn kan ri pe oloogbe bu s'ẹrin lẹẹmeji ní Akin Funmilayo ti òun naa wa pelu wọn ṣe fura pe ẹjẹ ruru ni nnkan to ṣẹlẹ tí o sì gbabẹ lọ sọrun.

Bakan naa ni ogbontarigi aṣere Yoruba ni, Rose Odika naa sọrọ pupọ nipa oloogbe Ola Ibironke.

Rose Odika ni pe Oloogbe naa jẹ ẹni to ni iwa tutu nigba aye rẹ.

O ṣapejuwe rẹ bii: Ẹni to maa ń ro ire kan eeyan nigba gbogbo to dẹ nifẹ si awọn kan iyawo rẹ .

Rose ni pe iku oloogbe ba gbogbo wa lojiji ti o si dun wa gidi gan an ni.

Oríṣun àwòrán, others

Wo bí ọlọ́jọ́ ṣe dé fún Ola Ibironke, olówó orí Bimbo Oshin àti ibi tó parí iṣẹ́ sí

Ohun ti eeyan ba fẹran ni mọni lara.

Ola Ibironke parí ìrìnàjò rẹ̀ síbi tó fẹ́ràn láti máa lọ, Ibadan Gulf Club

Egbẹ Ibadan Golf Club ti oloogbe Ola Ibironke jẹ eekan nibẹ ti fi ọrọ lede nipa iku ẹni wọn to lọ.

Àkọlé fídíò,

Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Ninu atẹjade naa ni wọn ti ni pe olowo ori Bimbo Oshin deede subu ni ki ọlọjọ to de.

Wọn ni nkan bii aago mẹjọ abọ alẹ ọjọ Aiku naa ni ìsẹlẹ yii ṣẹlẹ.

Koda, wọn ni Dudu Heritage wa pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni gbagede golf club ni Ibadan ni lasiko ti ọlọjọ kan ilẹkun, bẹẹ ko si ẹni to ri ti ọlọjọ ṣe.

Awọn ẹgbẹ Dudu Heritage sọ pe wọn sare gbe akọni ọkunrin óhun lọ sile iwosan ki wọn to ni ẹpa ko boro mọ.

Koda, wọn ni ilaji ni asia yoo wa nibẹ ati pe ko ni si eto idaraya kankan lasiko yii lati fi ṣe ẹyẹ fun un.

Yoruba bọ wọn ni ọjọ a ba ku laa di ere. Bi iroyin iku gbajugbaja to n gbé iṣẹ́ olórin síta tó ṣáláìsí, Ola Ibironke ti ọpọ mọ si Dudu Heritage Production ṣe jade ni ọpọ oṣere ti n ṣe idaro.

Àkọlé fídíò,

Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

Ẹwẹ, aworan oloogbe to ṣalaisi yii ko fibẹ wọpọ loju opo awọn oṣere, dipo bẹẹ aworan akẹgbẹ wọn Bimbo Oshin ni ọpọ wọn n fọn sori ayelujara lati baa kẹdun tori oun ni o kangun si wọn gangan.

Eyi ni awọn ololufẹ awọn oṣere ri ti wọn n beere pe ṣebi ọkọ rẹ lo ku, ewo ni aworan rẹ ti gbogbo oṣere wa n gbe saye.

Wo àwọn òṣèré tó ń fi àwòrán Bimbo Oshin kẹ́dùn ikú Dudu Heritage

Iroyin taa gbọ ni pe lọdun 2005 ni Ola Ibironke gbe gbajugbaja oṣere Bimbo Oshin niyawo.

Lara awọn oṣere akẹgbẹ Bimbo to n kii ku idaro Dudu Heritage niyi ti ọpọlọpọ wọn n gbadura fun oun ati idile wọn ti wọn si n gbaa niyanju lati mu ọkan le.

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Opeyemi Aiyeola

Oríṣun àwòrán, Seilat

Àkọlé fídíò,

Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn

Oríṣun àwòrán, Mercy Aigbe

O ka Faithia Balogun lara to bẹẹ to jẹ pe aworan ẹkun lo fi si oju opo tirẹ.

Oríṣun àwòrán, Opeyemi Aiyeola