EFCC Raid: Gbájúẹ̀ 56 ni ọwọ́ tẹ̀ ni òtẹ́lì àti àwọn bùba mííràn nípìnlẹ̀ Ogun

EFCC Raid: Gbájúẹ̀ 56 ni ọwọ́ tẹ̀ ni òtẹ́lì àti àwọn bùba mííràn nípìnlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ikọ̀ àjọ tó n gbógunti ìwà ajẹ́bánu ní Nàìjíríà (EFCC), ti mú ènìyàn mẹ́rìndílọ́lọ́ta ni ilé ìtura ìjọba ìpínlẹ̀ ogun kan, Mitros Residence Annex ati àwọn ilé ìtura méjì mííràn ní ilú Abeokuta.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, àwọn já wọ ilé ìtura Mitros Residence Annex, ilé ìtura tó ni yàrá mọ́kàndínlọ́gọ́ta ni gómìnà nà àná ni ìpińlẹ̀ Ogun Ibikunle Amosun kọ́ kí Dapo Abiodun to gbàá.

Ìròyìn sọ pé, bí aago mẹ́rin ìdájí ni àwọn EFCC já wọ awọn yàrá ni ilé ìtura náà lọ́jọ́ ajẹ́ tí wọ́n sì mú àwọn tó gbà yàrá tí wọ́n funra sí pé gbájúẹ̀ orí ayélujára niwọn.

Àbẹ̀wò àwọn oníròyìn sí ilé ìtura náà lọ́jọ́ ajé ṣe afihàn àwọn tó gba yàra sí ilé ìtura náà si n duro ka ni èjèèjì tí wọ́n sì ǹ sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ to wáyé.

Ní àyíka ilé ìtura náà pẹ̀lú, àwọn oníròyìn àkíyèsí pé, ìdaji ilékun àti àwọn àwo lo ti fọ́ kù sílẹ̀ níbẹ̀.

Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtura náà ṣàlàyé pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ gbájúẹ̀ orí ayélujára náà ló sálọ́ nígbà tí ọwọ́ tẹ àwọn mííràn ti àjọ EFCC gbé wọn lọ.

Obìnrin kan lára àwọn to wà níbẹ̀ sọ pé, wọ́n kó fóònù mẹ́fà níní yàrá kan lásìkò tí EFCC wá tìbọn-tìbọn ni yàra ti òun wà pẹ̀lú olólùfẹ́ òun.

Ọmọbinrin náà ṣàlàyé pé, olólùfẹ́ òun wà lára àwọn tí wan kò rí mú lásìkò náà, sùgbọ́n gbogbo àwọn ohu èlò àti ọkọ̀ rẹ ni wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé.

"A o tilẹ̀ gbọ́ nǹkankan, afi ìgbà ti wọ́n pa ẹ̀rọ amúná wá ni a tó mọ̀ pé wàhálà ń lọ lọ́wọ́, pàápàá julọ nígbà ti a gbọ́ ẹkún ẹnìkan"

" Ẹ ni ti mo wà pẹ̀lú sálọ sùgbọ́n wọ́n ti gbé mótò rẹ̀."

Ẹ̀wẹ̀, olórí ọ̀rọ̀ tó n lọ fún àjọ EFCC, ẹ̀ka ti Ibadan, ọ̀gbẹ́ni Tokunbo Odeniyi fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

Odeniyin ni " Bẹ́ẹ̀ ni a mú awọn gbájúẹ̀ orí ayélujára kan ni Abeokuta ní olúùlú ìpínlẹ̀ Ogun