Igogo Festival: Àwọn nǹkan to máa n jẹyọ lásìkò ọdún Igogo ni ipinlẹ Ondo

Àwọn nǹkan to máa n jẹyọ lásìkò ọdún Igogo ni ipinlẹ Ondo

Ilu Ọ̀wọ̀ nipinlẹ Ondo wa ninu pọpọṣinṣin ọdun Igogo bi Kabiyesi Ọlọwọ yoo ṣe jade loni.Ọdun Igogo to ti le ni ẹgbẹta ọdun jẹ ọkan lara awọn ọdun ibilẹ to gbajumọ julọ nipinlẹ Ondo ati ni iwọ-oorun-guusu orilẹ ede yi.Ọdun Igogo ni wọn n ṣe ni iranti Ọ̀rọnṣẹ̀n, ti o jẹ arẹwa, ọlọrọ, ati alagbara aya Ọlọwọ Rẹ̀nrẹ̀ngẹnjẹ̀n, ti wọn si wipe ọpọ ogun ni o ti ọkọ rẹ lẹyin lati bori.

Lati kopa ninu ọdun Igogo, awọn ọkunrin yio dirun wọn, wọn o si tun wọṣọ obirin pẹlu akun loriṣiriṣi.Wiwe gele ati dide fila, to fimọ ilu lilu pẹlu ibọn yinyin ni ko si igbalaaye fun lakoko ọdun yi, ni bo ṣe jẹ pe agogo nikan ni wọn maa n lu lakoko ọdun Igogo.

Igogo ọdun yi ni ikeji ti Ọba Ajibade Ogunoye kẹta to jẹ Ọlọwọ kejilelọgbọn yio ṣe bii ọba lẹyin to gun ori itẹ awọn babanla rẹ ni ọdun 2019.Layajọ ọjọ oni, Ọba Ogunoye ti yio dirun rẹ, ti yio si tun wọṣọ bi obirin pẹlu ọpọlọpọ akun ni yio dari awọn araalu ninu iwọde kaakiri ilu titi de aafin Ọjọmọlúdà ilu Ijẹbu ati awọn aaye to lapẹrẹ laarin ilu.