Council Of Obas: Akeredolu yan Deji Akure gẹ́gẹ́ bi alága ìgbìmọ̀ àwọn ọba ni Ondo

Akeredolu yan Deji Akure gẹ́gẹ́ bi alága ìgbìmọ̀ àwọn ọba ni Ondo

Gómìnà ìpińlẹ̀ Ondo Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti buwalu ìyànsípò Deji Akure Oba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi gẹ́gẹ́ bi alága ìgbìmọ́ àwọn lọ́balọ́ba ní ìpińlẹ̀ Ondo.

Wọ́n yan Aladelusi lẹ́yin tí ọba tó wà nipò náà parí sáà ọdún méjì, ìyẹn ọba Fredick Eniolorunda Obateru Akinruntan to jẹ́ Olugbo ti Ugbo tí wọ́n yà ni ọja kẹtàlá, oṣù késan-án ọdún 2021.

Àtẹ̀jáde tó kéde ọba náà fi kun pé, ìpo náà bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹsán, ọdún 2021.

Gómìnà Akeredolu dúpẹ́ lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ àwọn labálọ́ba lábẹ ìdari Olugbo ti Ugbo tó fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó kù láti ran ìjọba lọ́wọ́ fún ànfàní àrá ilú.

Gọ́mìnà wá rọ alága tuntun láti tún ṣe ribiribi ju ǹnkan ti àsááju rẹ tí ṣe tẹ́lẹ̀ lọ, pàápàá julọ láti kó àwọn ọba tó kù rín gẹ́gẹ́ bi ọmọ ìyá kí ìdàgbàsókè ba le bá ìṣètò ìjọba.