Amotekun: Ọwọ́ Amotekun tẹ àwọn afurasí tó gbé òkú lọ́wọ́ láìsí orí lára rẹ̀

Awọn afurasi ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Amotekun Oyo

Ọwọ ikọ Amotekunn ipinlẹ Oyo ti tẹ awọn ajinigbe kan, ti wọn ta ori eeyan fun awọn to fẹ ṣe oogun owo niluu Ibadan.

Amotekun ka oku okunrin ẹni ọdun mẹtalelaadọrin kan mọ awọn afurasi naa lọwọ, lẹyin ti wọn ti ge ori rẹ fun ẹni to fẹ fi joogun.

Agbẹnusọ fun ikọ Amotekun ipinlẹ Oyo sọ fun awọn akọroyin pe, olugbohun ni awọn ajinigbe naa n lo lati fi ba awọn eeyan sọrọ ki wọn to lọ gbe wọn pa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Ẹnikẹni ti wọn ba ti fi olugbohun ba sọrọ yoo tẹle wọn lẹsẹ kan naa lọ si ibikibi ti wọn ba n fẹ ko tẹle wọn lọ."

"Wọn ji okunrin ẹni ọdun mẹtalelaadọrin kan gbe ni alẹ, ṣugbọn wọn fi silẹ titi di ọjọ keji ki wọn mu lọ sinu yara kan nibi ti wọn ti ge ori rẹ, nigba ti awọn meji to ku di ẹsẹ rẹ mu.

Àkọlé fídíò,

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

Gẹgẹ bi ohun to sọ, ile alfaa kan ni wọn ti ge ori rẹ fun ẹni to fẹ fi ṣe oogun owo.

O ni "Lẹyin ti wọn ge ori rẹ tan wọn gbe fun okunrin kan to gbe ori naa lọ sile rẹ nibi to ti jo ori naa ninu ikoko, pẹlu erongba lati fi ṣe oogun owo, ṣugbọn gbogbo wọn ti wa ahamọ wa bayii."

Ẹwẹ, ọkan lara awọn afurasi naa ti wọn fẹsun kan pe oun gan lo ṣekupa oloogbe ọhun ṣalaye pe ẹgbẹrun marundinlogoji naira ni oun gba lati ge ori oloogbe naa.

O ni "Wọn wa ba mi pe awọn nilo ori eeyan, mo si mu wọn lọ sọdọ alfaa, ti alfaa naa si mu wa lọ sọdọ ẹnikan ni ọja Bode."

"Ọjọ keji ni alfaa mu ẹnikan ti wọn ti fi oogun ba sọrọ wa ti a si pa, o ni ki n di ẹsẹ rẹ mu lasiko ti a n ge ori rẹ ninu yara alafaa."

Afurasi ọhun sọ siwaju si pe "Lẹyin ti wọn fun mi ni ori naa ni mo gbe lọ sile, mo si jo ninu ikoko pẹlu erongba lati fi ṣe oogun owo."

Wayi o, igbakeji adari ikọ Amọtẹkun ipinlẹ, Kazeem Babalola ni awọn yoo fa awọn afurasi ọhun le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii ni kikun, ki wọn si tun le foju bale ẹjọ.

Àkọlé fídíò,

Jẹ́ ká lọ sílu mi: Kò sí ìtàn Ibadan láìsí Efunsetan, Òkè méje, Bower's Tower àtàwọn ǹkan