Gani Adams: Bí Buhari bá ń yáwó lemọ́lemọ́, òpin yóò dé bá Naijria láìpẹ́

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, aareganiadams

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba Iba Gani Adams, ti bu ẹnu atẹ lu bi ijọba aapọ ṣe n ya owo lemọ-lemọ lati ilẹ okeere.

O ni bi ijọba apapọ ṣe n jẹ gbese yii le ko Naijiiria sinu wahala ti irandiran awọn araalu yoo maa san fun ọpọ ọdun.

Gani Adams lo sọ ọrọ naa nibi ọdun Egbe, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ to waye lagbegbe Ibeju-Lekki, niluu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ti ijọba to wa lode ko ba lagbara lati san awọn gbese naa, yoo jẹ ohun ajogunba fun awọn ijọba miran to n bọ lẹyin rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ ni ko buru ju ti ijọba ba n ya owo, ṣugbọn ewu n bẹ loko longẹ Naijiria bi ijọba apapọ ṣe n ya owo lai ṣeto bi yoo ṣe san awọn owo naa pada.

Àkọlé fídíò,

Atunto Naijiria la n fẹ - Aarẹ Onakakanfo, Gani Adams

Aarẹ sọ pe "Lọsẹ to kọja, Aarẹ Muhammadu Buhari kọwe lati ya biliọnu mẹrin dọla, ṣugbọn o gbagbe pe ori awọn ọmọ Naijiria ni ẹru wuwo gbese naa yoo wa."

"Gẹgẹ bii ohun ti ijọba apapọ sọ, wọn yoo fi owo naa kọ oju ọna reluwee lati ilu Kano lọ si orilẹ-ede Niger Republic, ijọba apapọ tun sọ pe akanṣe iṣẹ naa yoo ṣe awọn araalu lanfaani nitori yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje laarin Naijiria, Niger atawọn orilẹ-ede to wa ni Ariwa ilẹ Afrika."

"Ṣugbọn o yẹ ki a mọ pe inira nla ni gbogbo gbese yii yoo mu ba awọn eeyan kaka ko tun igbe aye wọn ṣe."

Gani Adams tun sọ siwaju si pe ijọba apapọ ba oju ọna marosẹ Eko si Ibadan ku lati nnkan bi ọsun mejila sẹyin, bẹẹ naa ni ọna Eko si Badagry.

Sugbọn o ni ijọba gba lati maa ya owo lati ṣe ọna oju irin lati Kano si Niger, eyii ti ko ni ṣe anfaani kankan fun awọn ọmọ Naijiria.

Aarẹ Ona Kakanfo pari ọrọ rẹ pe, igbesẹ ijọba apapọ yii da bi igba ti eeyan ba fi ẹtẹ silẹ, to si lọ n bojuto lapapa ni.

Àkọlé fídíò,

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́