Nigeria Restructuring: Adebanjọ ní Buhari mọ̀ọ́mọ̀ kẹ̀yìn sí ìlérí rẹ̀ láti ṣètò àtúntò ilẹ̀ yìí ni

Ayo Adebanjo ati Bola Tinubu

Adarí ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ni Nàìjíríà, olóyè Ayo Adebanjo, ti fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ó ṣeéṣe kí Nàìjíríà má le e ni ìtẹ̀síwájú tàbí ìdàgbàsókè, tí wọn kò bá ṣe àtúṣe si ìwé òfin Nàìjíríà sáájú ìdìbò ọdún 2023.

Bákan náà ló tún kéde pé, "bí ó jẹ́ ọmọ mi ló fẹ́ dupò ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kankan ní Nàìjíríà, mí o ni gbárúkù tí, tí kò bá sí àtúntò Nàìjíríà".

Agba ọjẹ náà tún ké sí aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ni Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu láti ṣètò bí àtúntò yóò ṣe bá Nàìjíríà kí ó tó máa rónú láti jádé fún ipò ààrẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú àtẹ́jáde kan tí o fí síta l'Ọjọ́rú, ó n sọ̀rọ̀ nibi ìpáde ẹgbẹ́ Yorùbá Global Council, ti wọn pé akọ́le rẹ̀ ni "The Platform"

Ó ní ìràn Yorùbá sì gbà pé ìṣèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari mọ̀ọ́mọ̀ kọtí ọ̀gbọin sí ọ̀rọ̀ àtúntò Nàìjíríà ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó jẹ ọ̀kan pàtàki lára ọ̀rọ̀ ìpòlongo rẹ̀.

Àkọlé fídíò,

Nigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....

Adebanjo, lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ nípà ìpinu Asiwaju Ahmed Tinubu láti di ààrẹ Nàìjíríà, ló ti gbàá nímọ̀ràn pé, kí ó tó dí ẹni ti ẹgbẹ́ yóò gbà láàyè láti díjẹ̀ lábẹ́ APC, ó ṣe pàtàkì láti kọ́kọ́ dúnadúrà pẹ̀lú ààrẹ Buhari lórí àtúntò Nàìjíríà.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé, àbẹ̀wò òun si Bola Tinubu nígbà tó dé láti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, kìí ṣe nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú, bí kò se láti lọ kíí gẹ́gẹ́ bi ọmọ Yorùbá ṣe ń ṣe.

Olórí ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re náà tún kígbe pé, àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn yóò ṣe àtúntò Nàìjíríà lásìkò ìpolongo ìbò lọ́dún 2015, sùgbọ́n ó ṣe ni láànú pé, wọn kò mú ilérí wọn ṣẹ lẹ́yìn ti ààrẹ Buhari wọlé tán.

"Kódà àwọn tó gba ipò, tí wọn si n pè fún àtúntò ìjọba, àwọn ènìyàn bi Tinubu, Segun Osoba, Bisi Akande, sùgbọ́n lẹ́yìn tí wọn gba ipò tán, wọn ni àtútò kìí se pàtàkì lórí àwọn ètò tí àwọn ń ṣe.

"Mo rọ̀ yín pé kí ẹ pe Bola Tinubu, Segun Osoba, Bisi Akande àti àwọn mííràn sí gbàgede yìí bákan náà, ẹ bi wọn pé kí ló dé tí wọn fi yà kúrò, ẹ rọ wọn kí wọ́n bá Buhari sọ̀rọ̀ láti ṣe àtúntò Nàìjíríà saájú kí àsìkò ìdìbò ọdún 2023 tó dé.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà