Rotten Tomatoes: Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Rotten Tomatoes: Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Onimọ nipa fifi ounjẹ wo aisan, Olusola Malomo ti ṣalaye idi ti ko fi yẹ ki awọn eeyan to ba fẹ ra Tòmátò ni ọja maa ra ẹsa Tomato to ba ti fi ara kan isalẹ apẹrẹ.

O jẹ ko di mimọ pe ko dara fun ilera eeyan rara labẹ gbogbo akoso bo ti wu ko ri.

Ipo ti ipese ounjẹ fi n ja walẹ lati bii ọdun melo kan sẹyin to fi mọ jija walẹ iyi owo ati bi ìṣẹ́ ṣe n pọ sii ti mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria maa ra awọn ounjẹ to ti n bajẹ pẹlu ero ati jẹ ẹ bẹẹ bẹẹ.

Iroyin bojuwo bi awọn onibara kan ṣe pinu lati bẹrẹ si maa ra Tomato to ti n bajẹ tabi fọ lara gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ tori pe o dinwo ju oju eyi to ṣi n dan lara lọ ati pe yoo pọ diẹ ju u lọ.

Lara awọn to n ra a ti pupọ ninu wọn jẹ awọn to n se ounjẹ ta ṣalaye pe bi eeyan ba ti fọ ọ daadaa ti eeyan si bọ ọ lori ina, ṣe ni yoo da wa ni ilera pada to si dara fun jijẹ.

Ẹwẹ, onimọ nipa ounjẹ jijẹ fun ilera, Olusola Malomo sọ fun BBC Yoruba ohun to ṣe pataki fun ilera eeyan nipa ẹsa ti awọn mii yan lati maa ra yii.