Sunday Igboho: Àwọn ọlọ́paàá dí agbègbè iléeṣẹ́ ìjọ́ba Benin Republic táwọn 'Yoruba nation' fẹ́ lọ ṣe iwọ́de fún ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, BBC/igboho/instagram
Ni oṣu keje ọdun 2021 ni awọn agbofinro mu Igboho ati iyawo rẹ lorilẹede Benin republic nigba to n gbiyanju ati lọ si orilẹede Germany
Nṣe lawọn ọlọpaa di agbegbe ti olu ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Benin republic wa lagbegbe Victoria Island nibi ti awọn ololufẹ Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti gbero ati ṣe iwọde.
Awọn oluwọde naa ni awọn wa sileeṣẹ aṣoju ijọba Benin Republic naa lati rawọ ẹbẹ si ijọba orilẹede Benin republic ki wọn tuu silẹ ninu ahamọ to wa nilu Cotonou.
Ni oṣu keje ọdun 2021 ni awọn agbofinro mu Igboho ati iyawo rẹ lorilẹede Benin republic nigba to n gbiyanju ati lọ si orilẹede Germany lẹyin ti awọn oṣiṣẹ agbofinro DSS ya bo ile rẹ ni ọjọ kinni oṣu keje kan naa.
- Ọlọ́pàá ti kó àwọn afurasí tí wọ́n bá òkú Demilade nínú 'cooler' nílé wọ́n ni Ekiti lọ sílé ẹjọ́
- "Àwọn agbésùmọ́mí ló ń ṣe ìjọba lé wa lórí, kìí ṣe ìjọba Nàìjíríà tí Buhari ń darí"
- Èèyàn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jesu gún pasítọ̀ ìjọ RCCG pa nínú ṣọ́ọ́ṣì l'Eko
- Ọkùnrin kan pokùn so lẹ́yìn tó pàdánù N150,000 owó iléèṣẹ́ sórí tẹ́tẹ́
Lati igba yii wa ni Igboho ti wa lahamọ ijọba lorilẹede Benin lẹyin ti wọn tu iyawo rẹ silẹ.
Awọn oluwọde naa ko lee de ọfiisi aṣoju ijọba orilẹede Benin lati fi ẹdun wọn han pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe di opopona to lọsibẹ pa.
Ninu ọrọ ti wọn ba awọn akọroyin sọ ni oritamẹta to wọ agbegbe naa, awọn adari awọn oluwọde naa ke si awọn ijba orilẹede Benin republic pe ki wọn dakun-dabọ tu Igboho silẹ
Arakunrin Ṣobọwale Samuel ṣalaye pe erdi wiwa wọn ko ba wahala wa bikoṣe lati ke si gbogbo awọn ọtọkulu lati dide fun itusilẹ Sunday Igboho.
FUTA First Class Twins
"lootọ ija ilu ni Sunday Igboho n ja fun, ṣugbọn bi awọn ọmọ Naijiria ba ni awọn ko ṣetan, ki wọn maa binu, ki wọn fi Igboho silẹ ko lọ ṣetọju ara rẹ."
Ọ̀ga ọlọpaa to lewaju awọn ọlọpaa to lọ sibi iwọde naa ṣalaye pe gẹgẹ bi ọlọpaa, awọn mọ pe gbogbo awọn ọmọ Naijiria lo lẹtọ labẹ ofin lati wọde fi sọ ẹhonu wọn ṣugbọn ohun ti ofin agbaye sọ ni pe iwaju ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede kan ti di ara ilẹ orilẹede naa, nitori naa wọn ko lee fi aye silẹ fun ẹnikẹni lati lọsori ilẹ orilẹede Benin republic lati lọmaa wọde nibẹ.