Èsù ló ti mi láti san #2,650 fun owó mótò "Camry Muscle"- Afurasí

Oríṣun àwòrán, Insight media
Ẹní ọdún mẹ́àdílọ́gbọ̀n kan, Abdulazeez Tunde Ibrahim, ti ṣàlàyé bi ó ṣe ra mọ́tò "Toyota Camry" ti gbogbo ènìyàn mọsí "Muscle" pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún méjì àti àdọ́ọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta Náírà.
Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé mọ́tò náà lé ni mílíọnù éjì àti ẹgbẹrún lọ́nà ẹgbẹ̀ta Nàìrà, Ibrahim tan ẹni ti o ń ta mótò náà nílùú Osogbo ti o si gbé mótò náà lọ
Ibrahim jẹ́ ọ̀kan lára àwọn afurasí, mẹ́wàá ti kọmisọnà ọlọ́pàá Wale Olokode fi ojú wọn hàn ni olu ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìlú Osogbo lọ́jọ́ Ẹti.
- Arákùnrin kan r'ẹ́wọ̀n ọdún 24 he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹlú ọmọ ìkókó
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun dóòlà ọmọ ọdún méje tí alágbàtọ́ rẹ̀ n fìyà jẹ
- Èèyàn àti ẹbọra ló péjù-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ogún ọdún tí Eniola Badmus ti n ṣeré ìtàgé
- Ọlọ́pàá ti kó àwọn afurasí tí wọ́n bá òkú Demilade nínú 'cooler' nílé wọ́n ni Ekiti lọ sílé ẹjọ́
wọ́n ń fi mi pamọ́ ni lásìkò ti mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alága nítorí ọmọdé ni mí
Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ ọkùnrin náà lọ si ibi ti wọ́n tí n ta mọ́tò ti o sí nàka si ọkọ̀ ti o yàn láàyò, wan dúna dúrà iyé ti wọ́n tàá
Lẹ́yìn ìdúnadúrà yìí ni àwọn méjèèjì ti gba pé mílíọ̀ù méjì àti ẹgbẹ̀rún lọ́ọ́nà ẹ̀gbẹ̀ta, ó le ààdọ́tà Nàìra ni.
Sùgbọ́n kàkà kí ó fi iye owó yìí ránṣẹ, o fi ẹgbẹ̀rún méjì àti àdọ́ọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta Náírà sọ̀wọ̀ si ẹni náà, lẹ́yìn ti ẹnbi tí ó n ta ọkọ̀ náà sì ti ri pé ó sanwó wọlé lóòtọ́, ó fún ni ìwé èrí pé ó sànwó ti o sì gbé mótò nàá lọ ilé àwọn ti ó n kùú lọ́dà.
Kọmísọ̀nà ọlọ́pàá ni nígbà tó yá ni ẹni tó n ta ọkọ̀ ṣẹ̀ọ̀ẹ̀ mẹ̀ pé, iye tí o yẹ kí o wọlé kọ ló wọlé àti pé ẹgblrún méjì àti àdọ́ọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta Náíra lo fi ṣọwọ́ sí òun, lóba gbé agọ́ ọlọ́pàá lọ lati lọ fẹjọ́ sùn.
Olokoda ni lẹ́yìn èyí ni àwọn ọtẹ̀lẹmúyẹ́ lépa rẹ̀ lọ sí Iwo níbi ti mọ́tò náà wà níle àwọn to n kùn-ún
Ẹni ti ó ń kun ọkọ̀ náà Olayinka Bashir náà wà lára àwọn ti wọ́n mú ti wọ́n si fi si àhámọ́ pẹ̀lú Ibrahim Abdulazeez.
Bákan náà ni ọlọ́pàá tún mú àwọn ọkùnrin mẹ́rin mííràn Sunday Olajide, Hammed Semiu, Salawudeen Lukman àti Isiaka Salawudeen fún pípa ob]inrin kan láti lòó fún ògùn owó