Ogun Pastor rapes choir member: Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni, mi ò jẹ̀bi

Atọna Christ Apostolic Bible Church

Wọn ti gbe ijọ Christ Apostolic Bible Church, CABC, to wa ni Alaja Oke, Saje, to wa niluu Abeokuta tipa lẹyin ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan pasitọ ijọ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun sọ pe awọn ṣe iwadii pasitọ ijọ onaa pẹlu iyawo rẹ lẹyin ti awọn mejeji jọ gbimọpọ pe ki pasitọ ọhun fi ipa ba ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin rẹ sun.

Ṣugbọn pasitọ naa ti sọ pe ọrọ ọhun ko ri bi awọn eeyan ṣe lero.

Pastọ naa, Peter Taiwo ti sọ pe ọrọ ifẹ wa laarin oun ati ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti wọn ni o fi ipa balopọ tẹlẹ.

O ni "Mo sọ fun pe ko fi ọrẹkunrin rẹ silẹ, ati pe n oo maa fun ni ohunkohun to ba fẹ."

Gẹgẹ bii ohun ti pasitọ naa sọ, ọmọ ọhun fi ẹsẹ ṣeṣe, oun si n gbiyanju lati ba wa itọju fun ẹsẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network

O ni lẹyin ti nọọsi to n tọju ẹsẹ rẹ sọ pe ọrọ naa ti n kọja agbara rẹ, ni oun sọ pe oun yoo ba ti ẹsẹ ile bọ nipa adura gbigba.

"Emi ati ọmọ naa sunmọ ara wa gidi, koda, o maa n wa sinu iyẹwu mi loorekoore."

"Nigba to wa sinu iyẹwu mi fun ayẹwo ẹsẹ naa, mi o mọ ẹmi to ba lemi."

"Lati igba naa wa lo ti maa n fi awọn atẹjiṣẹ ololufẹ ṣọwọ si mi, ti emi naa yoo si fesi pada… awọn atẹjiṣẹ naa ṣi wa lori ẹrọ ilewọ mi titi di akoko yii."

Pasito Peter sọ pe oun ko ba ọmọ naa ṣere ifẹ lati igba naa wa ṣugbọn awọn mejeji fẹran ara wọn gidi.

Àkọlé fídíò,

Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

O ni "Nigba naa to ba ti wa sọdọ mi, a kii ṣere ifẹ, ṣugbọn nigba mii a maa fi ọwọ pa ara wa lara, nigba mii ẹwẹ mo maa n sọ pe ko fi ẹnu ko mi lẹnu."

Pasitọ naa jẹwọ pe oun ba ọmọ naa ṣere ifẹ ati pe oun bun iyawo oun gbọ pe ki o ba oun bẹẹ ki ọrọ naa ma ba di ariwo.

"Nigba ti a ṣere ifẹ, mo sọ fun kiyawo mi pe ko darijin mi, ko si tun ba mi bẹ ọmọ naa."

Ẹwẹ, nigba ti iyawo pasitọ naa yoo fesi, o ni oun ko mọ pe ere ifẹ wa laarin ọmọ ti ọrọ kan ati ọkọ oun.

Ki ni iyawo pasitọ sọ?

Gẹgẹ bii ohun ti iyawo pasitọ naa sọ, o ti le lọdun marundinlogun ti awọn mejeji ti wa gẹgẹ bii tọkọ-taya, wọn si bi ọmọ mẹta.

Iyawo rẹ sọ pe o gba iṣẹ Oluwa ni nnkan bii ọdun marun un sẹyin nigba ti wọn ni ko gbọ ipe Oluwa.

"Emi ni ọga ẹgbẹ akọrin, awa meje ni a ninu ẹgbẹ akọrin naa, obinrin mẹta ati okunrin mẹrin… ọmọ ti a n wi yii naa jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ akọrin."

Àkọlé fídíò,

Mariam Balogun kunlekunle to fi gboorọ jẹka laarin awọn akẹgbẹ rẹ

Obinrin naa sọ pe nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni oun ba ọmọ naa ninu iyẹwu ọkọ oun pẹlu ẹjọ lori ibusuin rẹ, ti ọmọ naa si n wa ẹkun mu.

O ni igba naa ni oun mọ pe nnkan ti ṣẹlẹ, oun si ke gbajare amọ ọkọ oun bẹbẹ pe ki wọn ṣe ọrọ naa ni oku oru.

Ki ni iya ọmọ naa sọ?

Iya ọmọ naa sọ fun BBC pe oun gan ni oun fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

O ni "O ba ọmọ mi lopọ, emi ni mo si fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ki wọn to fi ṣikun ofin mu."

"Emi ni mo ran niṣẹ lọjọ naa, nigba ti ko tet de ti mo lọ bẹẹ wo nile pasitọ naa ni mo ri ti wọn ti ba lopọ ti mo si ke gbajare.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ninu atẹjade ti agbenusọ rẹ, Abimbola Oyeyemi fi lede, o ni iwadii ti n lọ lọwọ, awọn tọkọ-taya naa yoo si foju bale ẹjọ laipẹ.

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

'Ìyàwó Pásítọ̀ wa ló tàn mí wọlé tó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ mi kí ọkọ rẹ̀ lè fi ipá bá mi lò'

Ile- Isẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu olusọ-aguntan kan ati iyawo rẹ nitori wọn gbimọ pọ lati ki ọkọ rẹ le fipa ba ọmọ ọdun mẹrindinlogun to wa ninu ẹgbẹ akọrin lopọ.

Ni ọjọ kẹwaa, oṣu kejila ọdun 2021, ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun mú Pasitọ Peter Taiwo ti ijọ Christ Apostolic Bible Church Alaja Oke, Saje Ni ilu Abeokuta ati iyawo rẹ Elizabeth Taiwo.

Wọn mu tọkọtaya yii lẹyin ti ọmọdebinrin naa mu ẹjọ lọ si agọ ọlọpaa olu ile ise ọlọpaa to wa ni agbegbe Adatan ṣalaye pe, ipade awọn akọrin ni oun lọ nigba ti iyawo pasitọ pe oun wọle pe pasitọ fẹ ran oun niṣe.

Àkọlé fídíò,

'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pllú omíjé kíkorò ...'

O ni iyawo pasitọ ni ki oun wọ yara lọ ba pasitọ nitori o ni iṣẹ to fẹ ran oun lati ṣe.

Ọmọbinrin náà ni kete ti oun wọle, iyawo pasitọ gan lo ti ilẹkun mọ awọn sinu ile lati ita, lẹyin eyi ni pásitọ fi agbara mu un ti o si fi ipa ba oun lo pọ.

Ọmọ naa fi kun un pe lẹyin ti pasitọ ti tẹ ara rẹ lọrun tan ti oun si bẹrẹ si ni sunkun ni iyawo pasitọ de to si sọ fun oun pe, oun ti di obinrin niyẹn ti pe ki oun nu oju oun nu.

O ni iyawo pasito ni oun ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni o, nitori ti oun ba sọ iku ni yoo jasi fun oun.

Lẹyin ti ọmọdebinrin yii mẹjọ lọ si agọ ọlọpaa ni DPO agọ ọlọpaa Adetan SP Salawudeeen Abiodun ran awọn ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ rẹ lọ si ibẹ ti wọn si fi ọwọ ofin mu pasitọ naa ati iyawo rẹ.

Lasiko ti wọn n fi ọrọ wa wọn lẹnuwo àwọn tọkọtaya naa jẹwọ pe awọn se ti wọn si da ẹbi ọrọ naa ru pe esu ni o faa.

Ninu atẹjade ti agbénusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fọwọsi lo ti sọ pe awọn tọkọtaya naa tọrọ aforiji lọwọ ọmọ naa pe ki o ma binu.

Wọ́n ti gbe ọmọ naa lọ si ile iwosan fun ayẹwo ati itọju ti o yẹ

Ẹwẹ Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka ọdaran to fi ọmọ ṣe owo ẹru ti fifi ọmọ sisẹ lọna aitọ fun ifọrọwabilẹnuwo ki wọn si gbe wọn lọ si ile ẹjọ