Libya returnee: Bàbá mi àti ìyá mi gbàgbọ́ nínú ẹ̀gbọ́n mi ló ṣe ní kí Bọ́dá méjì kan láti Kano mú mi wá Libya

Libya returnee: Bàbá mi àti ìyá mi gbàgbọ́ nínú ẹ̀gbọ́n mi ló ṣe ní kí Bọ́dá méjì kan láti Kano mú mi wá Libya

"Lẹyin ti awọn Bọda meji ara Kano to n gbe mi lọ fipa ba mi lopọ, mo sọ fun ẹgbọn mi to wa ni Libya aamọ o ni ko sohun to kan oun ju ki n tete de wa ba oun lọ".

Tolulope ko lee gbagbọ pe ọmọ iya oun, ọmọ baba oun lee hu iru iwa ti o hu si oun yii.

O ṣalaye lootọ fun BBC Yoruba wipe ko tilẹ wu oun lati lọ si orilẹede ti ẹgbọn oun wa rara amọ ọla wipe awọn jẹ ọmọ iya ọmọ baba ni oun ṣe gba ti iya oun naa si fọwọ sii.

Koda awọn eeyan naa tun n bii pe ṣe o da a loju pe ẹjẹ kan naa ni oun ati ẹni to n ṣe iru eleyi si i, o ni "bẹẹ ni".

Nigba ti yoo fi de Libya, ẹgbọn rẹ sọ ọ di ọmọ ọdọ lọwọ kan.

Alaye mii ti Tolulopẹ sọ ni pe oun ati ẹgbọn oun yii o jọ gbe nibi kan naa, toripe iya wọn ati baba wọn ti pinya ti awọn naa si tẹle wọn lọkọọkan.

Koko oun to jẹ ko tẹle e lọ ni pe o sọ fun iya rẹ ati baba rẹ pe oun fẹ ki aburo oun wa, Tolulope gba lati lọ ko lee maa fi owo to ba ri nibi iṣẹ daadaa to ro pe oun yoo maa ṣe tọju awọn aburo tirẹ.

"Igba to di oru ọjọ kan ni ọkan ninu awọn Bọda Kano yẹn wa ba mi to fọwọ bo mi lẹnu ti si fipa ba mi lopọ".

O ni ẹgbọn oun ko tilẹ kọbi ara sii nigba ti o ṣalaye fun un pe wọn fipa ba oun lopọ, o ṣaa fẹ ki oun maa bọ ni Libya ni.

Tolulope ṣalaye bi irinajo rẹ ṣe ri lati inu aginju de ile agbode-gba kan ni Libya ko to de ọdọ ẹgbọn rẹ toun naa bẹrẹ si ni gbe e kiri ile awọn "Arabu" liriṣiriṣi lati ṣe ọmọ ọdọ pẹlu iya ati idẹyẹsi oniruuru.