Gwagwalada gas explosion: Bí ìjàmbá iná gàásì mú ẹ̀mí ọmọdé méjì lọ nílùú Abuja

Ija ina

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ọmọde meji ti padanu ẹmi wọn nilu Abuja leyin ti ina gaasi bugbamu mọ wọn lọjọ Satide.

Iroyin sọ pe ni agbegbe Gwagwalada ni ijamba ina ọhun ti ṣẹlẹ.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe sọọbu kan ti wọn ti n ta gaasi idana lo fa a.

O ni lasiko ti ọkùnrin oni gaasi n da onibaara rẹ kan loun ni atẹgun gbe afẹ́fẹ́ gaasi lọ si sọọbu to wa ni ẹgbẹ́ rẹ, ti ina si sọ.

Àkọlé fídíò,

'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pllú omíjé kíkorò ...'

"Obinrin kan ti wọn n pe ni Iya Biliki lo ni sọọbu naa, to si lọ si ọjà lasiko ti isele naa waye, àmọ́ ti awọn ọmọ rẹ n se oúnjẹ ti wọn fẹ jẹ lọwọ.

"Ọmọ mẹfa ni ọmọ iya Biliki, àwọn mẹfẹẹfa lo si jona pupọ, àmọ́ eyi to kere ju lara wọn to sun sinu sọọbu ni ina jo pa. Bakan naa ni ọmọdé kan to wa ra 'pure water' naa jona kú."

Yàtọ̀ si awọn to kú tabi jona, ina gaasi naa tun jo sọọbu bii mẹrin.