Black Axe: BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Nàìjìríà àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn

Iwadii ọlọdun meji kan ti BBC ṣe lori Black Axe ree - ẹgbẹ awọn ọmọ ile-iwe Naijiria kan ti o wa di ẹgbẹ ti awọn eniyan ni ibẹru fun gidi.
BBC ti ṣe awari ẹri tuntun pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọ inu iṣelu, ati ipaniyan kaakiri agbaye.
Lẹyin idakẹjẹ diẹ, lẹyin ti o ti pari idanilẹkọ fun ọjọ naa, Dr John Stone salaye awọn nnkan ti o ti se gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ okunkun Black Axe.
- Kí ló kàn báyìí lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ ọmọ ogun orí omi Nàìjíríà (Navy) tú Cute Abiola sílẹ̀?
- 'Lójú mi, ọmọ ìyá mẹ́fà jóná, ọkàn kú nínú iná gàásì nílùú Abuja'
- Ọmọ Nàíjíríà tako Nafdac lórí ọ̀rọ̀ Codine
- Ẹ má ṣe dári ọmọ Yorùbá láti dìbò fún olóṣèlú kankan - Obasanjọ sọ fún Ooni Ife
- Rahmon Adedoyin ti sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìwádìí òkú ‘autopsy’ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura rẹ̀ nílé Ifẹ̀
'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pllú omíjé kíkorò ...'
"Kìí ṣe ẹ̀jẹ̀ tàbí ìró ìbọn náà ló ń dà á láàmú. Iranti bi awọn eniyan se maa n bẹẹ ni.
Bí àwọn èèyàn ṣe máa ń tọrọ àánú nígbà tí wọ́n bá fẹ kú. Ti wọn a maa bẹ ẹ ti wọn a tun maa bẹ Ọlọrun.
"O jẹ irora pupọ," o sọ, o mi ori rẹ pẹlu ibanujẹ. "Awọn idile awọn to ti ku, wọn yoo fi ọ bú. Egún wọn yoo wa lori aye rẹ."
Ọmọwe Stone ń kọ́ni ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ òṣèlú ní Yunifásítì ti Benin, ní gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà.
Ṣugbọn fun bi ọdun mẹwa o jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Black Axe - ẹgbẹ kan ti o ni iwa ọdaran ti o si ma n ko ipaya ba ara ilu ni orilẹ-ede Naijiria .
Bakan naa ni wọn so mọ ifini ṣe owo ẹru, jibiti ori ayelujara intanẹẹti ati ipaniyan.
Ni abẹlẹ, wọn maa n tọka si Black Axe bi "egbe okunkun," osuba randẹ ni fun bi wọn se maa n fa awọn eniyan si ilana ipilẹṣẹ aṣiri wọn ati iṣootọ nla ti awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
Wọn tun jẹ olokiki fun iwa-ipa nla ti wọn maa n hu.
Bakan naa lo ṣafihan oku awọn ti wọn ba ti kọja aye wọn niwaju ẹgbẹ okunkun naa - tí wọ́n ti gé awọn eniyan wẹlẹwẹlẹ tàbí ki wọ́n fi apa si wọn lara, gbogbo isẹ wọn yii lo máa ń tàn kálẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Ọmọwe Stone jẹwọ pe oun ṣe alabapin ninu awọn iwa ika lasiko to jẹ "Axeman" ninu ẹgbẹ Aye ti awọn Yorubba maa n pe ni Aake.
Ni asiko kan ninu ifọrọwanilẹnuwo wa, ni iranti awọn ọna ṣiṣe ti o muna doko julọ lati pa eniyan , o tẹ awọn ika ọwọ rẹ lati se apẹrẹ bi ibon ṣe maa n ri ti o si na si ori oludari iṣẹ iwadi wa.
Ni Ilu Benin, wọn mọ ọ si "alapatà".
Ìpayà ni àwọn ọdún wọ̀nyí ti jẹ fún. Loni, Ọmọwe Stone kabamọ gbogbo nnkan ti o ti se lati ẹyin wa ti o si ń bu ẹnu atẹ lu ti ẹgbẹ onijagidijagan ti o ti fi igba kan ṣiṣẹ fun tẹlẹ.
O jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe ti o ti pinnu lati ba ibura ti o ti se fun awọn ẹgbe rẹ jẹ ati lati tu asiri fun awọn oniroyin agbaye bi BBC, igba akọkọ.
Fun bi ọdun meji ni BBC Africa Eye ti n ṣewadii Black Axe, ti n fimu file lati se akojọ awọn to mọ asiri ẹgbẹ okunkun naa ati awọn ti yoo se ṣiṣafihan orisirisi awọn iwe assiri
Awon awari ti a ṣe daba pe ni ọdun melo seyin, Black Axe ti di awọn awọn ẹgbẹ ilufin ti o lewu ni julọ ni agbaye
Ni Afirika, Yuroopu, Asia ati Ariwa America, "Axemen" wa laarin wa. O le ti gba lẹt ninu meeli rẹ lati ọdọ wọn ri. Iwadii wa bẹrẹ pẹlu ihalẹ iku mọni - wọn kọ lẹt bi igba ti alantakun ba kọwe ransẹ, ti a si fi iru rẹ ranṣẹ si akọroyin BBC kan ni ọdun 2018.
Alupupu kan ni o ju iwe ọhun sori ọkọ ayọkẹlẹ oniroyin naa.
Ni ọsẹ diẹ saaju asiko yii, akọroyin naa ti n wadii awọn iṣowo ti ko tẹlé ilana ofin ni Nigeria ati pe o ti pade ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe lojukoju lasiko naa.
Lẹ́yìn náà, wọ́n fi lẹ́tà kejì ranṣẹ si ẹbi akọroyin naa. Ẹnikan ti n tọpa rẹ ati pe o ti ri ile rẹ.
Ṣe irọkẹkẹ naa wa lati ọdọ awọn Black Axe? Bawo ni itakun waọn se lagbara to, ati pe tani o wa lẹyin rẹ?
Iwadii wa fun awọn idahun nkan ti o ru wa loju mu wa lọ si ọdọ ọkunrin kan ti o sọ pe o ti ri ẹgbẹlẹgbé awọn iwe asiri Black Axe
Awọn itakutrọsọ ati ibaraẹnisọrọ ikọkọ, lati ọdọ ọgọọgọrun awọn ọmọ ẹgbẹ ti a fura si yii.
Awọn iwe asiri ifiranṣẹ naa, eyiti o wa lati ọdun 2009 si 2019, pẹlu awọn ibaraẹnisọrọ nipa ipaniyan ati ilokulo oogun.
Awọn meeli ṣe alaye lori iwa jibiti lori intanẹẹti ati bi o se ni ere lori to.
Awọn ifiranṣẹ gbero bi wọn yoo se tan kalẹ agbaye.
O jẹ iwa ọdaran awọn Black Axe ti wọn si n pinn awọn igboegbodo wọn kaarin awọn igun mẹrin agbaye,
Awọn orisun iwadii naa sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe ni pinu lati pa òun. Ko ni fi oruko re han, dipo o lo oruko apeso - Uche Tobias.
"Iku n bọ wa pa ọ," ni ihalẹ iku kan ka ti wọn kọ ransẹ si, ti a firanṣẹ si Tobias lori ayelujara.
" Ẹgbẹ Ake yoo fọ ori rẹ ti wọn yoo si la gbogbo ọpọlọ rẹ si meji… Emi yoo la ẹjẹ rẹ emi o jẹ oju rẹ."
BBC lo awọn oṣu diẹ lati ṣe itupalẹ awọn iwe ti Tobias ri yii.
A ni anfani lati mọ daju awọn apakan ẹri nnkan pe awọn ẹni-kọọkan mẹnuba, ati nọmba kan ti awọn isẹ ọdaran ti o ṣe ninu awọn iwe aṣẹ, to fi mọ ibi ti o ti waye.
Pupọ ninu ẹri ti a ri yii jẹ ohun to bani lẹru pupọ ti o si nira lati gbejade.
"Axemen" lo awọn apejọ aṣiri - awọn oju opo wẹẹbu ti o ni aabo ọrọ igbaniwọle - lati pin awọn fọto ti awọn ipaniyanwọn waye ti wọn yoo si fi akọle "Hit" sibẹ.
Ọkunrin kan dubulẹ lori ilẹ ni yara kekere kan. Ọgbẹ nla mẹrin wa lori rẹ ti aṣọ funfun ti o wọ i kun fun ẹjẹ
Awọn Isamisi ti a bata, abariwon pupa, samisi rẹ pada.
Láàárín Nàìjíríà, Black Axe ń bá awọn ẹgbẹ okunkun to ku pe awọn ni ọga wọn - irú àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú orúkọ bí Eiye, Buccaneers, Pirates àti Maphites.
Awọn ifiranṣẹ ti BBC ti tumọ lati Iwọ-oorun Africa paapaa julọ ni Pidgin fihan pe Axemen ti n tọju iye awọn abanidije ti wọn ti pa, wọn a si maa ka bi ẹni pe wọn n ka nọmba aami bọọlu ni agbegbe kọọkan.
"iye ti wọn ti jẹ bayii 15-2 lọwọlọwọ, ogun ti wọn n ja ni Benin," ninu atẹjisẹ kan ti wọn fi sọwọ.
"Hit" ni ipinle Anambra Iye ti a ti pa [Axemen] 4 ati Buccaneers 2, "bi atẹjisẹ mi ṣe fi han.
Ṣugbọn jibiti intanẹẹti, tabi ipaniyan ni o jẹ orisun ibi ti wọn ti n ri owo fun ẹgbẹ onijagidijagan naa.
Awọn iwe aṣẹ ti a fun BBC pẹlu jé awọn risiiti, bi wọn se fi owo ransẹ ati ọpọ awọn meeli ti n ṣafihan awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe ti n ṣe ifowosowopo lori awọn itanijẹ ori ayelujara ni agbaye.
Awọn ọmọ ẹgbẹ pin "awọn meeli nipa bi wọn yoo se gba awọn eniyan lori ayelujara laarin ara wọn.
Ara nnkan ti ma n ṣe ni lati fi ṣe ifẹ ẹtan han si awọn eniyan lori ayelujara, Wọn tun tan awọn eniyan lati gba ogun wọn, awọn itanjẹ ohun ini to jẹ ile ati ilẹ to fi mọ ki wọn maa fi meeli ẹtan ransẹ nipa iṣowo.
Awọn oluṣewadii ṣẹda awọn akọọlẹ imeeli ti o dabi ti awọn agbẹjọro ti olufaragba, tabi awọn oniṣiro, lati le gba awọn sisanwo.
Awọn ọna itanjẹ wọnyi kii ṣe keremi rara, ti o n waye nipasẹ eeyan bi Ikooko lori kọǹpútà alágbèéká kan.
Wọn maa n ni ifọwọsowọpọ, ti wọ́n si ma n lo awọn dọsinni alaba jọ sisṣẹpọ lati igun mẹrẹrin agbaye.
Lara awọn meeli to lu sita, BBC ṣe awari bi wọn se gba okunrin kan ni California nipasẹ agbarijọ awọn afurasi Axemen ni ọdun 2010, ti wọ si tanjẹ lati Italy ati Nigeria.
Ọkunrin naa sọ fun wa pe wọn lu oun ni jibiti $3m lapapọ.
"Banki ti mo n ṣiṣẹ pẹlu dabi pe ko tilẹ si laye yii rara???" awọn ọkunrn naa n sọrọ pẹlu inira pẹlu ọasn ninu awọn meeli to fi sọwọ- ni kete ti o mọ pe wọn ti gba òun " Se ki n laa ye yin??? ọpọ awọn banki to wa ni Switzerland wa fun iwa ọdaran.
Awọn imeeli ṣe afihan pe awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe ti a furasi saba maa n lo awọn orukọ to le mu ni" - awọn orukọ ti kii se orukọ wọn gan ati awọn idamọ - nigbati wọn ba n tan awọn eniyan jẹ, wọn ma n lo awọn iwe irinna ayederu ti wọn ji.
Wọn tọka si awọn ti wọn tan jẹ bi "mugu" tabi "maga," awọn ọrọ to tumọ si "òmùgọ" labẹle"
O ṣeeṣe ki itankun awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe lagbaye n ri ọkẹ àìmọye dọla to n wiwọle fun wọn ninu iṣẹ jibiti ori ayelujara ti wọn n ṣe.
Ni ọdun 2017 awọn alaṣẹ orilede Canada sọ pe wọn latiko ti awọn lu igbimọ owọn oni jibiti ori aryelujara to sọ pẹ mo ẹgbẹ yii awọn ri asiri owo to to biliọnu marun dọla ($5bn).
Ko si ẹnikan ti o mọ iye awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun Black Axe ti o ti wa lawujọ.
Awọn iwe to lu sita yii ṣe afihan awọn ọmọ ẹgbẹ ti n ba ara wọn ni ibaraẹnisọrọ laarin Nigeria, UK, Malaysia, Gulf States, ati awọn orilẹ-ede mejila miiran.
"O ti tan kaakiri agbaye,"iwadii ti a se fidi eyi mulẹ fun wa.
O sọ pe o jẹ olusewadi iwa -jegudujera ni igbesi aye ikọkọ oun, o bẹrẹ si lepa Black Axe lẹyin ti o ba awọn ti wọn ti tanjẹ sọrọ pẹlu ọkẹ aimọye owo ti wọn ti gba lọwọ wọn
"Emi yoo ṣe iṣiro pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa yoo to ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti o si le ju bẹẹ lọ.
Wọn se agbégbekalẹ ẹgbẹ Black Axe kári agbaye pẹlu ọgbọn inu wọ́n si fi ara balẹ lati gbe kalẹ.
Awọn eto wọn fihan pe awọn Axemen pin awọn ẹgbẹ wọn si agbegbe "awọn agbegbe," ati yiyan awọn "ori" agbegbe.
Awọn olori agbegbe n gba "owo ori" - ohun kan ti o jọmọ awọn owo ọmọ ẹgbẹ - lati ọdọ awọn ti o wa ni agbegbe wọn, ki wọn to fi owo naa ranṣẹ pada si awọn alakoso ni ilu wọn ni Ilu Benin ni Nigeria.
"O ti tan kaakiri Yuroopu ati Amẹrika, South America ati Asia," gẹgẹ ni Tobias se sọ.
"Kii ṣe ẹgbẹ kekere rara, eyi jẹ ajọ igbimọ ọdaràn nla nla gan ni."
Ayẹwo Tobias ni atilẹyin iwadii awọn agbofin ro lagbaye.
Gẹgẹbi Atọka Ilufin Aṣeto ti Ọdun 2021, ti o da lori itupalẹ lati ọdọ awọn amoye ọgọfa ni Afirika, Naijiria lo ni ẹka awọn ọdaran to leto julọ paapaa julọ lori kọmputa - ati pe awọn itakun wọnyi n pọ si ni ilẹ okeere.
Ni orilede Italy, awọn oniruuru ofin ni wọn ti gbekalẹ fun ọdun pipẹ lati koju imugboroosi ẹgbe Black Axe, ti wọn sọ pe o jẹ ẹgbẹ arufin ti o si ti lagbara ju ti agbegbe lọ.
Ni Oṣu Kẹrin ọdun 2021, awọn ọgbọn ọmọ ẹgbẹ ti a fura si ni wọn mu ni orilẹ-ede naa, ti wọn fi ẹsun rira ati tita ifini ṣowo ẹru, iṣẹ aṣẹwo ati lilu jibiti lori ayelujara kan wọn.
Orilede Amerika tun mu ofin ti wọn wọn le diẹ si lati ri pe ko si aaye fun iru iwa bẹẹ.
Awọn osisẹ FBI sẹ agbekalẹ eto lati lodi si ẹgbẹ Black Axe ti wọn si ṣe ifilọlẹ rẹ ni Oṣu kọkanla ọdun 2019 ati Oṣu Kẹsan ọdun 2021, nikẹhin wọn fi ẹsun kan awọn eniyan marundinlogoji lori ẹsun iwa jibiti lori intanẹẹti to le to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu dola.
Laarin Oṣu Kẹsan ati Oṣu kejila ọdun yii, Ile-iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Amerika ati Interpol ṣe ifilọlẹ iṣẹ kariaye lati mu awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe mẹsan miiran ti wọn fura si ni South Africa.
"Iluni ni jibiti ori ayelujara jẹ wyi ti o se akojọpọ ọkẹaimọye-ọpọlọpọ tririliọnu dọla, ti ko ni si ni ẹni to n se iṣakoso rẹ," gẹgẹ bi Scott Augenbaum, aṣoju FBI nigba kan ri ti o si ti mọ nipa iwa jibiti ori ayelujara.
O ni oun ni nnkan sẹ pẹlu awọn ti ọmọ ẹgbẹ okunkun Black Axe ti ṣe lọsẹ ninu iriajo lẹnu iṣẹ rẹ fun bi ọgbọn ọdun ti o ti n ṣiṣẹ, ti o si n tọpasẹ awọn iwa jibiti lori ayelujara ti o si jọ mọ awọn eyi to jẹyọ ninu iwe asiri to jade.
" Mo ti ri bi aye awọn eniyan se bajẹ, ti awọn ile isẹ si parun, gbogbo owo ti ẹlomiran fi pamọ fun ọjọ iwaju lo lọ pata, O ni ọpọ eniyan ni ọrọ naa kan.
Bi ẹka awọn ọdaràn Black Axe se wu ki o gboooro to ti o si ni gbongbo sibẹ Naijiria ni orisun rẹ. Wọn ṣe idasilẹ ẹgbẹ naa ni ogoji ọdun sẹyin ni Ilu Benin, Ipinle Edo.
Ọpọ awọn "Axemen" yii wa lati agbegbe yii, ati pe eyi le ni ibaṣepọ to gbooro bi wọn se tan kariaye.
Gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà àjọ UN fún àwọn ton se atipo, ida aadọrin ọmọ Naijiria ti wọn rinrin ajo lọ si oke okun wa lati Ipinlẹ Edo
Iroyin ni Black Axe ni ipa pataki ti wọn n ko ninu isowo ifisẹru paapaa julọ awọn to n rin irin-ajo lọna aitọ, wọn maa n gbe wọn n laarin awọn ipilẹ wọn ni Ilu Benin, Ariwa Afirika ati Gusu Italy.
Ni ilu abinibi wọn, awọn ọmọ ile-iwe giga fasiti ti ọjọ-ori wọn ko ju ọdunmẹrindinlogun ati àti ọdun ọdun mẹtalelogun lọ - jẹ ọmọ ẹgbẹ Black Axe.
Ilana siṣe ọna ati fa ẹni wọ ẹgbẹ ikọkọ ẹgbẹ onijagidijagan, ti wọn maa n pe ni "bamming,"
"Emi o mọ pe mo n lọ bam lọjọ naa ni, " Gẹgẹ bi o se kọ, ọkan ninu awọn Axemen, sapejuwe iriri rẹ ninu ọrọ to kọ soju opo ikọkọ kan lọdun 2016.
O ni wọn sin oun kuro ninu ọgba ilé iwe ti oun si ro pe, oun lọ si pati alarinrin kan.
Ó kọ bí wọ́n ṣe gbé e lọ sínu igbó kan, níbi tí àwọn ọkùnrin gende ọmọ ẹgbẹ naa ti ń dúró dè é.
Wọ́n bọ́ asọ lọrun rẹ, wọ́n sì fipá mú un láti dojúbolẹ̀ nínú ẹrọfọ.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n n fi igi ọparun luu bi ẹni maa ku.
Ẹnikan pariwo pe wọn yoo fipa ba ọrẹbinrin rẹ lopọ, nigbati o ba ti pari, ohun naa yoo tun fipa ba obinrin miiran lopọ.
"Iyẹn yoo jẹ ọjọ ti Emi yoo ku," o kọọ soju opo naa. Ṣugbọn irora naa pada tan nikẹhin.
Ọpọlọpọ awọn ilana etutu lo tun tẹle ọjọ yii ti o fi mọ titọpasẹ awọn to n fi imu rẹ danrin - aṣa ti a mọ si "ọna eṣu" - ṣaaju mimu ẹjẹ lẹyin ti wọn ba ge ika rẹ ati jijẹ obi.
Won n kọrin, lẹyin naa awọn ọkunrin ti wọn ṣẹṣẹ fìyà jẹ ẹ tan yoo wa di mọọ. O ti di atunbi niyẹn eyi ti wọn n pe ni "Aye Axeman."
Idi ti ọpọ eniyan fi n darapọ mọ Black Axe pọ lọ jantirẹrẹ. Diẹ ninu awọntọ wọ ẹgbẹ naa ni wọn fi ipa mu nigba ti awọn miiran wọ pẹlu idunu wọn.
Ni Makoko, ti o jẹ gbungbu ibi ti awọn otosi pọ si, ti wọn si kọ ile wọn pẹlu igi ọparun lori omi ni ipinlẹ Eko.
A ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ Axemen, diẹ ninu awọn ti wọn sọ pe wọn darapọ mọ nitori awọn niifẹ si.
Sibẹ Iduroṣinṣin wọn, fun ẹgbẹ naa kọ lafui we - ti fi idi rẹ mulẹ nipasẹ etutu ti wọn se fun wọn.
"A ń jọ́sìn Korofo, Ọlọ́run tí a kò rí, ó sì máa ń tọ́ wa sọ́nà nígbà gbogbo," olórí ẹgbẹ́ náà lo sọ fún wa, nígbà tí ó jókòó sínú ilé kékeré kan tí a fi igi ṣe, tí àwọn ará Axemen kan si yí wa ká.
Ó ní o jẹ "iwuri" fun oun láti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Black Axe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́pàá kan ló mu oun wọ ẹgbẹ naa pẹlu tulasi.
Ọmọ ẹgbẹ miiran sọ pe oun darapọ mọ wọn lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun miiran pa baba oun.
Laibikita bii tabi idi ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ to darapọ lo ma n sọ pe awọn anfani wa ninu ẹgbẹ naa.
"Aṣiri, ibawi ati ifọwọsowọpọ bi ọmọ baba kan naa," ọmọ ẹgbẹ okunkun kan sọ fun wa pẹlu iwuri lakoko ifọrọwanilẹnuwo miiran ni Ilu Eko ni Oṣu Kẹrin ọdun 2021, nigba ti a beere idi ti o fi darapọ mọ Black Axe.
O sọ pe oun n ri owo ti o dara nipasẹ awọn iwa ọdaran ati jibiti - o si dara ju ki oun owo ti oun yoo gba ti oun ba n sisẹ ni banki.
Ko si ẹni ti yoo ke fi ọwọkan o ti o ba ti wa ninu ẹgbẹ naa, wọn yoo daabo bo ọ.
Ọrọ yii ni Curtis Ogbebor to jẹ sj fẹtọ ni ilu Benin sọ - ni kete ti o ba wa ninu ẹgbẹ okunkun, wọn yoo daabobo ọ. ti o n gbiyanju lati sọ fun awọn ọdọ pe didarapọ mọ ẹgbẹ okunkun ko ni ere paapaa julọ ẹgbẹ bi Axe.
"Asiko etutu yii ni wọn ma n lo fun titan awọn wọn kalẹ."
Dr Stone sọ pe ọpọlọpọ awọn Axemen darapọ mọ wọn nitori wọn fẹ mọ awọn eniyan nibi gigi wan si fẹ ta gbongbo kalẹ.
Orile-ede Naijiria ni ipo keji ti awọn ọdọ alainiṣẹ ti o ga julọ wa ni agbaye, ati pe bi eniyan ba dara pọ mọ ẹgbẹ Black Axe le pese aabo ati awọn ọna ti oko owo rẹ yoo fi ma lọ deede.
O sọ pe kii ṣe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lo jẹ ọdaràn.
"A ni awọn ọmọ ẹgbẹ ninu awọn ọmọ ogun Naijiria, awọn ọgagun oju omi, awọn ologun ori afẹfẹ.
A ni awọn ti o wa ni ile-ẹkọ giga gẹgẹ bi olukọ
A ni awọn alufaa, awọn oluso-aguntan, "gẹgẹ bi o se sọ.
Atilẹyin ibaraenisepọ yii jẹ pataki ti idid tin wọn fi da ẹgbẹ naa silẹ,
Ẹgbẹ naa jade lati inu awọn ọmọ ile-ẹkọ fasiti ti wọn si pe ni Neo Black Movement of Africa (NBM).
Fasitii Benin ni wọn ti da silẹ lọdun 1970.
Ẹgbẹ NBM jẹ awọn ẹwọn ãke dudu ti n fọ awọn ẹwọn, ati pe awọn oludasilẹ rẹ sọ pe ero wọn ni lati koju irẹjẹ.
NBM jẹ atilẹyin ijijagbara ni South Africa, ṣugbọn ni ọna, aṣiri ati ifaramọ arakunrin ẹni, o ṣe afihan awọn awujọ bii awọn Freemasons, eyiti o ni iwa laaye ni ni Nigeria lasiko ijọba amunisin.
NBM ṣi wa loni, ati pe o jẹ ile-iṣẹ ti o forukọsilẹ labẹ ofin pẹlu Igbimọ Ajọṣepọ Naijiria.
Wọn sọ pe awọn ni awọn ọmọ ẹgbẹ to le ni miliọnu mẹta ni agbaye, o si maa n ṣe ikede aanu nigbagbogbo - awọn ẹbun si awọn ile-iṣẹ alainiya, awọn ile-ẹkọ ati ọlọpaa, mejeeji ni Nigeria ati ni ilẹ okeere.
Wọn maa n ṣe awọn apejọ nla lọdọọdun, diẹ ninu eyiti awọn oloselu ati awọn gbajumọ maa n peju si.
Awọn oludari ti NBM sọ pe Black Axe jẹ rogue kan, ẹgbẹ fifọ. Ni gbangba wọn ya ara wọn kuro ni agbara lati orukọ ati pe wọn fẹsẹmulẹ pe NBM tako gbogbo iṣẹ ọdaràn.
"NBM kii ṣe Black Axe. NBM ko ni nkankan lati ṣe pẹlu iwa ọdaràn. NBM jẹ agbari ti o duro lati ṣe igbega nla ni agbaye," Olorogun Ese Kakor, Aare ẹgbẹ naa lọwọlọwọ se sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC ni Oṣu Keje, ọdun 2021.
Agbẹjọro NBM sọ fun wa pe ẹnikẹni lati inu Black Axe ti wọn ba ri pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ NBM "wọn yoo yọ kuro lẹsẹkẹsẹ" ati pe wọn ko ni ifarada fun iwa-ipa bẹẹ.
Awọn agbofinro agbaye ni wiwo ti o yatọ. Awọn alaye nipasẹ Ẹka Idajọ AMẸRIKA, lakoko ti ẹjọ rẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ Black Ax lati ọdun 2018, ti ṣalaye pe NBM jẹ "agbari ọdaràn" ati "apakan ti Black Axe". Awọn alaye ti o jọra ni a ti sọ nipasẹ awọn alaṣẹ ni Ilu Kanada, ti wọn ti sọ NBM ati Black Ax bi "kanna".
Awon agbajoro NBM sọ fun wa lati awọn Black Ax ti won ba ri pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ NBM "yoo yọ kuro ipa" ati pe won ko ni ifarada fun iwa-ipa.
Awon agbofinro ni agbaye n fi oju ọtọ wo iru iwa ipa bayii.
Ọrọ kan to jade lati Ẹka Idajọ ni llẹ Amerika lasiko ti o n sẹjọ awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe kan lati ọdun 2018, fi idi rẹ mulẹ pe ara ẹgbẹ okunkun ni awọn NBM jẹ "agbarijọ ọdaràn" ati "apakan ti Black Axe ni wọn jẹ".
Ọrọ to jọ eyi naa ti walati orilede Canada, ti wọn sọ pe NBM ati Black Axe jẹ "nkankan naa".
Bakan naa gbogbo eri ti BBClo mu asopọ ba ọrọ mejeji yii
Awọn meeli ti wọn ri lọwọ Agustus Eyeoyibo to jẹ arẹ ẹgbẹ NBM laarin ọdun 2012 ati 2016, iwadii naa fi han pe ọgbẹni Bemingo to jẹ ilumọọka olooko owo to tun ni ile itura ti lọwọ ninu jibiti ori ayelujara to lagbara gidi
Awọn meeli ti wọn ri ni akata Ọgbẹni Bemigho safihan pe o ti ṣe alabapin ninu awọn itanjẹ ogún ti o si dojukọ awọn ara ilu UK ati AMẸRIKA.
Awọn olufaragba naa sọ fun wa pe wọn ji wọn ni owo to ju $3.3m lọ.
A ri pe owo ti o ti lu ni jibiti sunmọ Miliọnu kan dọla, "bi iwe ifiranṣẹ kan se sọ, ti n tọka si olufaragba kan, ti a fi ranṣẹ si Ọgbẹni Bemigho nipasẹ alajọṣepọ ti a fura si pe wọn jọ n se isẹ.
Meeli naa ni orukọ kikun ti olufaragba naa, adirẹsi imeeli ati nọmba rẹ, ati awọn itọnisọna lori bi o ṣe le tẹsiwaju ninu ete itanjẹ naa.
Awọn iwe yii daba pe, Ọgbẹni Bemigho fi awọn ọna sise itanjẹ ranṣẹ si itakun awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ o kere ju nigba aadọta.
Ọkan ninu afiransẹ naa, jiroro nipa imugboro NBM, ni imọran pe o beere pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ ni lati ṣeto awọn ile isẹ aadojutofo ni ayika ati lagbaye lati le "ri ẹgbẹlẹgbẹ milọnu owo gba wọle".
Nigbati o ba nfiranṣẹ awọn ọmọ ẹgbẹ NBM ninu awọn imeeli, Ọgbẹni Bemigho n pe wọn ni "Aye Axemen". Ninu idahun kan, eyiti o dabi pe o ti firanṣẹ si Ọgbẹni Bemigho nipasẹ ojiṣẹ Facebook, o pe ni "alàgba Black Axe ti orilẹ-ede".
Nigbati o ba n fi ọrọ ransẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ NBM ninu meli naa, Bemigho n pe wọn ni "Aye Axemen".
Awọn naa si si maa n n pe ni oludari ẹgbẹ Black Axe ninu idahun kan ti wọn fi sọwọ loju opo Facebook
Ni ọdun 2019, ana Bemigho kan ni wọn fi ẹsun kiko owo ilu lọ si ilẹ okere lọna aitọ i o si le ni miliọnu kan pọun ni ilẹ gẹẹsi. Ọpọ awọn ile isẹ iroyin lo gbe igbẹjọ naa. ti ọpọ awọn o si n pe ni adari agba fun ẹgbẹ Black Axe ninu onirruru atẹjade.
Nigba ti BBC gbe ẹri yii jade adari ẹgbẹ NBM sọ pe awọn yoo wadii rẹ awọn yoo ati pe ẹnikẹni ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori awọn yoo fi jofin awọn yoo si yọ kuro ninu ọmọ ẹgbẹ awọn
Ọmọwe Stone n sapejuwe pe Black Axe ati NBM -jẹ ajọ kan naa.
O n sọrọ lati inu iriri. Kii ṣe ọmọ ẹgbẹ Black Axe nikan, ṣugbọn tun jẹ alaga laarin NBM ni agbegbe wọn ni Ilu Benin.
"O jẹ ọkan ati ikan naa," o sọ. "O kan jẹ iru ilana lati bo awọn asiri. O jẹ owo kan pẹlu awọn ẹgbẹ meji."
Ni ibamu si ọrọ Tobias, NBM ti jẹ ohun elo fun imugboro igbimọ ikọkọ ti Black Axe ni agbaye.
O sọ pe "ere ipari" ti NBM jẹ "lati yi ero ti gbogbo eniyan" ni i - lati tọju "ohun ti wọn jẹ gaan, eyiti o jẹ iwa ipa ".
Awọn ile-iṣẹ ti NBM n ṣiṣẹ labẹ orukọ ti forukọsilẹ ni agbaye, to fi mọ UK ati Canada.
O kere ju aaadọta oju opo Facebook, Instagram ati awọn YouTube ni o n lo iyatọ oniruuru orukọ yii, ni afikun si awọn akọọlẹ ile-iṣẹ naa.
Diẹ ninu awọn akọọlẹ ni diẹ sii ni ju awọn ọmọlẹyin ọgọrun lọna ẹgbẹrun lọ.
Awọn nnkan miiran ti o maa n itọkasi nnkan ti Black Axe je ni lilo - emoji bi ake, awọn fọto ti awọn eniyan ti o gbe ãke tabi ibon, ati lẹẹkọọkan ọrọ ibuwọlu "Aye Axemen!"
NBM ti fi idi ara rẹ mulẹ ni aṣeyọri bi ami iyasọtọ agbaye, ni awọn orilẹ-ede pupọ. Ni orilẹ-ede Naijiria, Dokita Stone sọ pe, ipa nẹtiwọọki naa gbooro si aaye iṣelu.
"Awọn ọmọ ẹgbẹ pupọ wa ni Ile-igbimọ Ile-igbimọ, paapaa awọn alaṣẹ," o sọ. "Eyi ni ohun ti Black Axe jẹ.
Eyi ni ohun ti NBM n waasu: wo ipo eyikeyi ti o mọ pe o ṣee ṣe fun eniyan."
Augustus Bemigho to je olori egbe NBM tẹlẹ - ti won sapejuwe ninu iwe ejo UK gege bi olori egbe Black Ax tele - dije du ipo ni ile igbimo asoju-sofin Naijiria lodun 2019, labẹ egbẹ oselu All Progressive Congress Party (APC).
Ajafẹtọ Curtis Ogbebor sọ pe iṣelu ipinlẹ Edo ti kun fun awọn ọmọ ẹgbẹ Black Ax. "Nigeria ni oselu mafia yii," o sọ. "Awọn oloselu wa, ijọba ni gbogbo awọn ipele, ṣe iwuri fun awọn ọdọ wa sinu aṣa."
Awọn oloṣelu orilẹede Naijiria, Ọgbẹni Ogbebor sọ pe, wọn gba awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe lati dẹruba awọn abanidije, ṣọ awọn apoti idibo, ati fi agbara mu awọn eniyan lati dibo. O ni nigba ti won ba ti wa nipo, won yoo maa san won ni ipo ijoba.
Owo yii ni wọn ti pin taara "nipasẹ Oloye Oṣiṣẹ nigba naa Hon. Sam Iredia" - ti o ti ku ni bayi.
Lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ agba ti NBM ni Ilu Eko, aṣoju ofin wọn fidi rẹ mulẹ pe "awọn oloselu pupọ" jẹ ọmọ ẹgbẹ.
O tesiwaju lati daruko Igbakeji Gomina ti Ipinle Edo, Philip Shaibu, fun apẹẹrẹ.
Aliu Hope, ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò NBM sọ pé: "Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ wa, kò sì sí ohun tó lè fara pa mọ́ nípa rẹ̀.
"Wọn ni ihamọra wọn, wọn fun wọn ni owo lakoko idibo, wọn si ṣe ileri ipinnu oselu fun wọn," o sọ.
Awọn iwe asiri meji, kan eyiti o dabi ẹni pe o ti tu lati awọn ibaraẹnisọrọ inu ti NBM, daba pe 35m naira (diẹ sii ju £ 64,000) ni a fi ranṣẹ si ajọ naa ni Ilu Benin lati "daabobo ibo" ati rii daju pe atilẹyin fun idibo gomina ni ọdun 2012.
Ni paṣipaarọ fun atilẹyin, awọn faili sọ "awọn iho 80 [ni] ti a pin si NBM Benin Zone fun iṣẹ lẹsẹkẹsẹ nipasẹ ijọba ipinlẹ".
Omo egbe ijoba ipinle Edo tele, nigba to n ba awon oniroyin agbaye soro fun igba akoko, ti wa siwaju lati fesi ifesewonse lori ifowosowopo ipinle Edo pelu iwa odaran to seto.
Tony Kabaka, ti o jẹwọ funrarẹ "Olukokoro" ati ọmọ ẹgbẹ NBM, lo awọn ọdun ṣiṣẹ fun ijọba ni Benin, titi di ọdun 2019.
Ni akoko yii, nipasẹ ile-iṣẹ rẹ Akugbe Ventures, o gba diẹ sii ju 7,000 agbowode, ti o n pese awọn biliọnu ni ilu Benin. wiwọle fun ipinle.
Lati igba ti o ti kuro ni iṣelu, Ọgbẹni Kabaka ti dojuko awọn igbiyanju ipaniyan leralera.
Ile nla rẹ, ile nla funfun kan pẹlu awọn ọwọn Romu, ni awọn ihò ọta ibọn kun.
"Ti o ba joko mi sọ pe, 'Ṣe o le ṣe idanimọ Black Ax ni ijọba?' Emi yoo ṣe idanimọ, "o sọ.
" Pupọ awọn oloselu, o fẹrẹ jẹ pe gbogbo eniyan ni o wa."
Ọgbẹni Kabaka sọ pe wọn beere lọwọ rẹ lati ṣe koriya awọn ẹgbẹ egbeokunkun lati ṣe iranlọwọ lati bori awọn idibo.
O sẹ pe ko ni ipa ninu iwa-ipa funrararẹ.
"Ti ijọba ba fẹ wa idibo wọn nilo wọn," o sọ.
"Cultism si tun wa nitori ijoba lowo, ati awọn ti o ni otitọ."
A rin irin-ajo lọ si Ilu Benin ni Oṣu Keje ọdun 2021 lati ṣe ifọrọwanilẹnuwo Igbakeji Gomina Philip Shaibu, ṣugbọn o kuna lẹẹmeji lati koju ifọrọwanilẹnuwo naa.
Nigba ti a ran ijoba ipinle Edo ati Ogbeni Shaibu si esun wa pe won ni ajosepo mo Black Axe, won ko fesi.
Dokita Stone gbagbọ pe awọn agbofinro Naijiria ati awọn oloselu ti wa pẹlu Black Ax lati koju wọn daradara.
Ojutu si iwa-ipa, o sọ pe, wa laarin egbeokunkun funrararẹ.
Oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ tẹlẹ nikan ti o lero pe ẹgbẹ naa ti lewu pupọ.
"Ohun ti awon kan wa fi darapo mo NBM ni lati darapo mo ninu igbejako aninilara," okan lara awon omo egbe ipade asiri kan ti tu sita fun BBC. "Ṣugbọn ni bayi, a ti fi aami si ẹgbẹ ọdaràn pẹlu ẹri gbogbo."
Ti abẹnu Black Ax awọn ibaraẹnisọrọ ti wa ni idalẹnu pẹlu iru ẹdun ọkan lati omo egbe.
"Emi ko di axeman lati gba aye, Mo ti di axeman ni ibere lati fraternize," sọ pé miiran post. "Jọwọ, da awọn ipaniyan wọnyi duro."
Awọn oludari ti NBM sọ pe wọn ti pinnu lati rii daju pe ajo naa duro ni otitọ si awọn ilana ipilẹ rẹ ati ṣe agbega alafia.
Ààrẹ ẹgbẹ́ náà báyìí, Olorogun Ese Kakor, sọ fún BBC pé kí wọ́n yan òun láti fòpin sí "àwọn arúfin" ọ̀daràn àti pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣe "ìpalára púpọ̀" fún àjọ náà.
Ni ibere lati mu igbiyanju yi fun iyipada, Dokita Stone ti ṣe agbekalẹ ohun ti o pe ni "Rainbow Coalition" - ẹgbẹ agbawi kan ti o jẹ ti awọn oṣooṣu atijọ, awọn ọmọ ilu Naijiria ti o ni ipa ati awọn ọjọgbọn.
Awọn ọmọ ẹgbẹ gbiyanju lati de-escalate aifokanbale nigba ti orogun onijagidijagan, ati ki o ti wa ni gbiyanju lati darí Black Ax si ọna kan diẹ alaafia ojo iwaju.
"Idasi Rainbow si awujọ ni lati dinku iwa-ọdaran," o sọ.
"Lati dinku oṣuwọn iku laarin awọn ọdọ, lati dinku oṣuwọn awọn opo ati awọn alainibaba."
Oludasile Rainbow, Chukwuka Omessah, fẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ Black Ax ronu lori awujọ ti wọn ṣẹda.
"Gbogbo eniyan ni ẹri-ọkan," o sọ.
"O le sẹ lori kamẹra, sẹ nigba gbogbo eniyan, ṣugbọn o ko le sẹ ni akoko idakẹjẹ rẹ - yoo jẹ ọ."
Dr Stone mọ pe titari Black Axesi ọna atunṣe jẹ iṣowo ti o lewu. O mọ pe awọn ẹlẹgbẹ rẹ tẹlẹ le wa fun u ni ọjọ kan.
Ó ṣe tán fún wọn tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀.
Ọjọgbọn naa tọju idà gigun ẹsẹ mẹta ti o farapamọ sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, ati ibon yiyan iwe-aṣẹ ni ile.
"Fun oluso ti ara ẹni, aabo ti ara ẹni," o sọ, pẹlu ẹrin-musẹ.
"Ti wọn ba tẹle mi, emi naa ko le tẹle wọn?"
Iwadii nipasẹ Charlie Northcott, Sam Juda ati Peter Macjob