Police kill Lagos mechanic?: Ọlọ́pàá ṣàlàyé lórí ìròyìn tó ní wọ́n yìnbọn pa mọkálíìkì

Aworan Hakeem Odumosu ati Promise

Oríṣun àwòrán, Hakeem Odumosu

Ọrọ ko rí bí awọn iwe iroyin ṣe kọ ọ sita o. Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa Eko, Adekunle Ajisebutu ni irọ ni, kii ṣe ọlọpaa lo yinbọ pa ọdọkunrin mọkaliiki naa.

Ọdọmọkunrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa, Promise Tochukwu, ti ku lẹyin ti iroyin sọ pe awọn ọlọpaa yinbọn ba a lori afara Opaleye, ni agbegbe Okoya, ipinlẹ Eko.

Iroyin sọ pe ikọ alaabo kan ti wọn pe lati wa pana ija igboro lagbegbe naa ni ọlọpaa to yinbọn mọ ọ wa.

Iwe iroyin The Punch jabọ pe ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣojú rẹ, Esther sọ pe obinrin kan ti ọrẹkunrin rẹ fi ìyà jẹ, to si pa lara, lo pe awọn ọlọpaa.

O ni asiko ti Promise n pada sile ni ọta ìbọn ba a.

Amọ agbẹnusọ Ọlọpaa Eko ti ba BBC sọrọ pe oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa amọ ọlọpaa kankan ko yinbọn pa ẹnikẹni ati pe o darukọ ikọ ologun OPMESA gẹgẹ bi aridaju ẹni to yinbọn pa mọkaliiki naa.

O ṣeeṣe ki awọn araalu miiran ma mọ iyatọ laarin awọn ikọ alaabo yii ati ọlọpaa ti wọn ṣe n ko gbogbo wọn pọ.

Àkọlé fídíò,

Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

"Owurọ ọjọ Aje ni iṣẹlẹ yii waye, mo ri ọmọbìnrin kan ti gbogbo ara rẹ n ṣẹjẹ nitosi afara Opaleye, oun lo si pe awọn ọlọpaa lati wa mu ọrẹkunrin rẹ to fiya jẹ.

Asiko yii ni Promise n kọja lọ si ọna ile iya àgbà rẹ lai mọ nkan to n sẹlẹ".

O 'ṣoju mi koro ni "Àwọn ọlọpaa ati soja naa sọ pe ko duro bi wọn ṣe ri. Ṣugbọn bi wọn ṣe kiyesi pe o n sún sẹyin bi ẹni to fẹ salọ, ọlọpaa kan lara wọn yinbọn mọ ni ẹsẹ."

Arabinrin Esther sọ pe oun ni oun mu iroyin naa lọ sile awọn ẹbi Promise.

Ibatan Promise kan, Agnes, sọ fun The Punch pe ile onisegun ibilẹ kan ni wọn sare gbe Promise lọ. Nibẹ si ni wọn ti yọ ọta ìbọn meji jade ni ẹsẹ rẹ.

O ṣalaye pe oju ọna lo ku si nigba ti wọn n gbe e lọ si ileewosan ijọba fun itọju ọgbẹ rẹ.

Ṣugbọn ninu iroyin miran, olori agbegbe naa kan sọ pe lootọ ni ọlọpaa yinbọn mọ ọmọkùnrin naa, àmọ́ ija igboro laarin awọn janduku ni wọn wa da si.

O ni obìnrin ni àwọn janduku naa n jasi. Ija naa si ti n waye fun ọjọ bii marun-un, ki wọn o to pe awọn ọlọpaa ati awọn fijilante lati fi opin si.

Ẹni naa sọ pe fijilante kan lo tọka si Promise, ti ọlọpaa fi yinbọn mọ.

Wọn ti sin oku rẹ bayii. Ileeṣẹ ọlọpaa ko si tii sọrọ boya lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.