Mariam Balogun house painter: Mo ti nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ kunlékunlé láti ìgbà tí mò ń ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Mass Comm
Ọpọ igba ni awọn eeyan maa n bere lọwọ mi pe "madam" ki lẹ n ṣe nibẹ yẹn, ti emi naa a s fun wọn pe a ni ka maa gbiyanju ẹ diẹ diẹ ni".
Mariam Balogun to jẹ obinrin to yan iṣẹ kunle kunle laayo ṣalaye ohun ti oju rẹ maa n ri laarin awọn ọkunrin ti wọn jọ n ṣiṣẹ kunlekunle.
Akẹkọgboye imọ Ẹkọ iroyin (Mass Communication) ni Mariam jẹ amọ o ni ifẹ gidi si ṣiṣe inu ile ati ita ile ni ọ̀ṣọ̀ eyi si ti muu da ile iṣẹ kan silẹ.
Ni ile iṣẹ rẹ, wọn n ṣe ọṣọ ara ogiri to n jẹ 3D panel, wọn n kun ile ni ọda bẹẹ si ni wọn n ṣe ilẹ ile lọ́ṣọ̀ọ́ ati orule POP.
Bo ṣe di oloriire niu iṣẹ yii laarin ọgọọrọ awọn ọkunrin ti wọn jọ n ṣe jẹ ipenija nla fun un.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ninu ifọrọwanilẹnu wo pataki kan, Mariam ranti awọn igba kan ti awọn ọkunrin ko gba fun un lati jẹ ọmọ ẹkọ́ṣẹ labẹ wọn nigba to n wa iṣẹ ọwọ to lee kọ lẹyin to pari ile ẹkọ giga.
Nigba to wa di akọṣẹmọṣẹ tan, Mariam ni ọpọlọpọ ọkunrin to wa ninu iṣẹ yii kan naa ni inu maa n saba bi nigba ti wọn ba n sọrọ aduru iṣẹ to n ri gba.
Ẹwẹ, o jẹ ko di mimọ pe ọpọlọpọ onibaara yala ọkunrin tabi obinrin lo maa fun obinrin oniṣẹ ọwọ to ba yan iṣẹ ti wọn mọ mọ ọkunrin lanfani to pọ.