Bishop Oyedepo: Ta ni ọkùnrin tó kù gììrì mọ́ àlùfáà ìjọ Living Faith lóríi pẹpẹ?

Biṣọọbu Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Intel Region

Idan orita ṣẹlẹ ninu ṣọọṣi Biṣọọbu David Oyedepo lasiko ti ọkunrin kan ṣadede ku giiri si ojiṣẹ Ọlọrun naa, to si gba ẹsẹ rẹ mu lori pẹpẹ iwaasu.

Fidio kan to n milẹ titi lori ayelujara lo ṣafihan bi okunrin naa, ti a ko tii mọ orukẹ rẹ ṣe lọ ku giiri ba alufaa ọhun.

Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ alaabo rẹ atawọn gende mii ninu ijọ ọhun lo gba Oyedepo lọwọ okunrin naa nigba to ku diẹ ko gbe ṣubu lori pẹpẹ.

Iṣẹlẹ naa waye ni olu ijọ ọhun, iyẹn ni Canaan land to wa ni ipinlẹ Ogun.

Bawo ni okunrin naa ṣe ri aye kọlu Biṣọọbu Oyedepo?

Ko si ẹni to le sọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye ni pato nitori awọn alaṣẹ ijọ ọhun ko sọ nnkankan nipa rẹ.

Amọ awọn eeyan kan sọ pe iṣẹlẹ naa waye ni ibẹrẹ oṣu Kejila ọdun yii, ṣaaju ipade adura Shiloh ti wọn ṣẹṣẹ pari.

Àkọlé fídíò,

Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network

Ninu fidio ọhun ni okunrin naa ti gba alufaa naa lẹsẹ mu, to si n fa, ṣugbọn awọn ẹsọ alaabo rẹ ko gba ki okunrin naa ṣe alufaa naa leṣe.

Awọn ẹṣọ alabo Biṣọọbu naa n sọ fun ara wọn pe ki wọn maṣe wọ wọ okunrin naa nilẹ turutu.

Ẹwẹ, titi di akoko yii, ko si ẹni to tii le sọ irufẹ ẹni ti okunrin to ku giiri mọ Biṣọọbu naa jẹ ati eredi to fi ṣe bẹẹ.

Tani Biṣọọbu Oyedepo?

Biṣọọbu Oyedepo jẹ ọkan lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun to lamilaaka ni Naijiria, o tun jẹ oniṣowo ati akọṣẹmọṣẹ ayaworan ile.

Ilu Omu-Aran, ni ipinlẹ Kwara lo ti wa.

Oun ni oludasilẹ ati alufaa agba ninu ijọ Living Faith Church Worldwide, ti ọpọ mọ si Winners Chapel.

Àkọlé fídíò,

Mariam Balogun kunlekunle to fi gboorọ jẹka laarin awọn akẹgbẹ rẹ

O bẹrẹ ijọ naa ni ilu Kaduna ni ọpọ ọdun sẹyin, ko to gbe olu ijọ naa lọ si Canaan Land, ni Ota, ni ipinlẹ Ogun.

Biṣọọbu Oyedepo jẹ ojiṣẹ Ọlọrun kan ti kii woju ẹnikẹni, o si maa n sọrọ bo ba ṣe ri ninu ọkan rẹ.

Ọpọ igba lo maa n sọko ọrọ si ijọba Naijiria ti wọn ko ba ṣe ojuṣe wọn.