OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

A fé ki wọn sọ nkan malegbagbe lorukọ Heritage ni Fasiti Ife ni- Baba Heritage, Isreal Ajibola Olanipekun.

Se ẹ ranti omodebinrin akékọọ Fasiti Obafemi Awolowo to wa nilu Ile Ife nipinle Osun to jabo sinu koto ile igbonse lasiko to n sa aṣọ lọwọ?

BBC Yoruba ti wa ẹbi rẹ kan ni Ibadan ti wọn n gbe.

BBC ti ba Isreal Ajibola to jẹ baba oloogbe naaa ati Iya rẹ sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Baba Heritage n beere fun idajo ododo ki iru eyi ma baa tun ṣẹlẹ ti ireti Obi yoo pin nitori aika nkan si awon kan ni Fasiti ti ọmọ ti n kawe.

O ni ki won fi ile tabi nkan nla sọ ori Heritage Ajibola ki orukọ re ma baa parun ni.

Nigba ti BBC Yoruba kan si awọn alaṣẹ Fasiti Obafemi Awolowo nibi ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ, awọn naa sọ nkan ti wọn mọ nipa rẹ ati igbiyanju Fasiti naa lati doola ẹmi Heritage Ajibola ki ẹlẹmii to gba a.

Alukoro Fasiti Ife, Abiodun Olanrewajusalaye ajọṣepọ to wa laarin OAU ati awọn alaṣẹ ile ti Heritage n gbe yii.

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ Fasiti OAU ni Ile Ife naa sọ ero ti wọn fun BBC lori iṣẹlẹ naa.