Eyitayo Oyekunle constructs Solar AC: Tí òòrùn bá lọlẹ̀, a ti ṣe ẹ̀rọ tó ti gba òòrùn sára tí yóò ṣíṣẹ́ di òru mọ́júmọ́
Pasitọ Eyitayo Oyekunle jẹ ọmọ orilẹede Naijiria to ti fi ọpọlọpọ ọdun wa ni orilẹede South Africa ko to pada wa sile.
Bo ṣe n ṣe iṣẹ ihinrere ti Ọlọrun pe e si ni ifẹ rẹ fun iṣẹ imọ ẹrọ n ga sii lojoojumọ.
Nigba to ṣi wa lorilẹede South Africa, o ṣalaye, o ni oun maa n ṣe iṣẹ aso itan pọ atawọn iṣẹ ọpọlọ mii fawọn ileeṣẹ amohunmaworan.
Lọrọ kan, iṣẹ fifi imọ ẹrọ to nkan pọ ko di odidi ni ọgbọn ori ti Ọlọrun fun un eyi to si pọ lorii rẹ gan amọ bo ṣe gbe oriṣiriṣi iwadii tuntun jade naa ni o ni ipe Ọlọrun n kọ si oun.
Bawo ni mo ṣe wa fẹ ko aduru ọgbọn ori yii danu ki n lọ maa waasu?
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Eyitayo ni oun gbiyanju titi ninu iṣẹ ọpọlọ ti oun mọ yii, ko fibẹẹ ni akọsilẹ aṣeyọri.
Ọrọ rẹ fihan pe aṣe inu iṣẹ iranṣẹ to ba bẹrẹ ni Ọlọrun yoo ti fun un ni imọ nla to nilo lati ṣagbejade ohun elo nla kan to fun un ni ọgbọn rẹ lati pese.
Eyitayo ni oun dari wa sile ni Naijiria o si bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ. Bo ṣe n ṣee lọ lo ni imọ tuntun de.
Pasitọ yii ni bi oun ṣe tẹsiwaju ninu iṣẹ iranṣẹ niyẹn to si ko awọn eeyan to ni imọ ninu iṣẹ ṣiṣe ẹrọ amuletutu to n lo ina oorun fi ṣagbara jade yatọ si eyi ti gbogbo eeyan n ra kiri to n lo in ọba.