Ghana: Iwọde waye lori ele owo epo

Oju popo ni orilẹede Ghana
Àkọlé àwòrán Awọn eeyan ti n fẹhonu han fun irora to ba wọn lori ele owo ori epo bẹntiroolu lorilẹede Ghana

Ẹkunwo epo bẹntiroolu to waye ni orilẹede Ghana laipẹ yii ti nfa ẹhonu bayii, tawọn oluwọde si ti fun ijọba orilẹede Ghana ni gbedeke ọsẹ meji lati fi mu ayipada ba ọwọngogo owo epo bẹntiroolu to waye lorilẹede naa.

Awọn oluwọde ọhun ti wọn ko si inu asọ pupa ati dudu, rin kaakiri awọn opopona to lorukọ nilu Accra, tii se olu ilu oruilẹede Ghana.

Àkọlé àwòrán Owo ori epo to gbẹnu soke ti se akoba fun owo ori ọja pẹlu

Lara awọn ohun ti wọn kọ si ara patako ti wọn gbe dani ni awọn ọrọ bii, 'Aarẹ tẹti si awọn awakọ', " Kii se ileri too se fun wa niyi', ati 'Aarẹ, ẹ din owo yi ku.'

Ohun ti wọn n pariwo ninu iwọde wọn ni wipe, bi owo epo se n gbe ẹnu lọ soke ni igbe aye n nira fun araalu nibẹ.

Kini iwadi BBC sọ?

Ninu ọrọ to ba Akọroyin BBC, Thomas Naadi sọ, oludari ajọ to n risi katakara epo lorilẹede Ghana, ọgbẹni Duncan Amoah ni wahala wa lori eto okoowo ọrọ epo.

"Owo osu lorilẹede yii ko le fi aaye silẹ fun ẹkunwo kankan lori epo. Ohun ta n beere ni pe ki ijọba o o yẹ owo ori ti wọn n fi si ori epo wo. Ni orilẹede Ghana loni, owo ori lita epo kan le ni dọla kan owo orilẹede Amẹrika lọ. Ti ọrọ ba si ti n di ti pe owo to kere ju ti osisẹ n gba ko ba lee ra lita epo kan, wahala wa niyen o."

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn araalu nke si aarẹ orilẹede Ghana lati tete gbe igbesẹ lori ọrọ ẹkunwo epo.

Awọn oluwọde naa wa n ke si ijọba lati din iye akanse owo ori to n fi si ori epo bẹntiroolu ku ni ida mẹẹdogun ninu ọgọrun.

Amọsa, ileesẹ epo rọbi orilẹede Ghana ti sọ wipe ohun ko lagbara lati sọ iye ti owo epo bẹntiroolu yoo ba de atipe gbogbo igbesẹ to yẹ ni gbigbe ni wọn ti gbe lati rii pọ ipa ẹkunwo naa dinku lara araalu.

Ireti wa wipe Aarẹ Akufo Addo yoo fesi si ọrọ ọhun lasiko ti yoo ba gbogbo awọn ọmọ orilẹede naa sọrọ ni ọjọọbọ.