Nigeria: Kiniun pa olusọ ọgba ẹranko

Ọgbeni Mustapha Adam ti Kiniun pa
Àkọlé àwòrán Igba keji ree ti kiniun yoo sekupa eeyan lorilẹede Naijiria

Olusọ ọgba eranko kan ti ku lẹyin igba ti kiniun kan kọlu ni ọgba ẹranko kan to wa nilu Kaduna lẹkun ariwa Naijiria.

Kiniun naa fi tipa-tipa jade ninu ile rẹ to wa ni ibudo igbafe Gamji to gbajumọ ni igboro Kaduna, nibi ti kiniun ná ti se Mustapha Adam l'ẹse l'ọrun.

Wọn gbe Ọgbeni Adam lọ sile iwosan nibi to ti faye silẹ nitori bo se sese lowuro kutu-kutu Ojoru.

Awon alase sọ wipe wọn tan kiniun naa pada si ibugbe rẹ lehin ikọlu naa.

Igbakeji ree ti kiniun yoo sa jade kuro ninu ile rẹ, ti yoo si sekupa eniyan lorilẹ̀ede Naijiria laarin osu mefa.

Ninu osu kesan ọdun to koja, kiniun kan pa ọkunrin kan ton fun ni ọunje nigboro ilu Ibadan.

Ni ọdun 2015 bakanaa, kiniun kan sa jade kuro ninu ile re ni igboro ilu Jos, sugbọn won pa-a, ko to se ẹnikeni lese.

Related Topics