Ile asofin agba buwọlu aba to fofin de tita siga leyọ ẹyọ

Awọn asofin n jiroro nile igbimo asofin - 2017 Image copyright National Assembly/Website
Àkọlé àwòrán Ile igbimọ Asofin agba ni ẹka asofin to ga julọ lorilẹede Naijiria

Idunnu subu layọ fawọn ajọ to n ja fun imọtoto ati alaafia agbegbe lorilẹede Naijiria (Environmental Rights Action ati Friends of the Earth Nigeria (ERA/FoEN) , nigbati ile igbimọ asofin agba buwọlu aba to fofin de asa siga tita lawọn agbegbe ile-ẹko alakọbẹrẹ ati ti girama.

Ile asofin agba buwọlu aba to fofin de tita siga leyọ ẹyọ

Adari ipolongo fun ajọ Environmental Rights Action ati ti Friends of the Earth Nigeria (ERA/FoEN) Philip Jakpor, nigba to n ba BBC sọrọ, wipe idunnu lo jẹ fun awọn nigba tawọn asofin agba fọwọsi aba lati fopin si tita siga layika ile-ẹko, ti ko si si eni to tako aba ofin naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIparọwa si gbogbo awọn tọrọ naa kan lati ri wipe aba ofin naa mulẹ lorilẹede Naijiria

Adari ipolongo naa wa parọwa si gbogbo awọn tọrọ naa kan lati ri wipe aba ofin naa mulẹ nigbogbo ẹka ati ẹya to wa lorilẹede yi, ki ọjọ iwaju awọn ọdọ le wuyi pẹlu ilọsiwaju to lamilaaka lorilẹede yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIgbese ti ajo ERA gbe lati koju tita siga lagbegbe ile ẹkọ

Senato Remi Tinubu, nigba to n ba ile igbimọ asofin agba sọrọ wipe, siga mimu le fa aisan jẹjẹrẹ ọna ọfun ati awọn aisan mii to le se ipalara fun ẹjẹ ati ọkan awọn eniyan. O si ran awọn asofin leti wipe sise ipolongo siga fun awon eniyan tako ofin orillẹede Naijiria lori isakoso taba fifin ti wọn n pe ni (Framework Convention on Tobacco Control (FCTC ) ati ti (National Tobacco Control Act ) tọdun 2015.