Ajọ isọkan agbaye sẹ ifilọlẹ iranwọ biliọnu dọla kan fun ariwa Naijiria

Aworan asalasala Image copyright STRINGER

Ajọ isọkan agbaye ti pẹ fun iranwọ biliọnu dọla kan lati ran ila oorun ariwa Naijiria lọwọ.

Agbegbe naa fara kaaṣa pupọ nibi ija Boko Haram ti o ti'n ṣ'ọsẹ lati bii ọdun mẹwa sẹyin .

Ile isẹ ajọ isọkan agbaye to'n se amojuto iranwọ fun awọn ti ajalu na kan sọ wi pẹ owo na yoo wa fun iranwọ pajawiri fun awọn to kagara julọ.

Eniyan to to miliọnu mẹjo lo nilo iranlọwọ larin ọdun yi nikan.

Ile isẹ ajọ isọkan agbaye naa so pẹ awọn nkoju ipẹnija fun pipese ounje latari bi rogbodiyan naa se peleke.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ikọlu Boko Haram ba ọpọlọpọ dukia jẹ ni agbegbe ariwa Naijiria

Ile isẹ naa to se ifilole iranwo naa ni olu ilu Naijiria, Abuja, sọ wi pẹ awọn yoo se ẹto naa pẹlu ifọwọsọwọpọ ijọba orilẹẹde yi ati awọn alajọsepọ lati ilẹ okere.

Ija Boko Haram ti sokunfa sisipo pada fun ogunlọgọ eniyan,bakana lo ba awọn oun elo amayedẹrun jẹ .