Ileeṣẹ ọkọ-ofurufu Dana d'awọn ero lẹbi ilẹkun to yọ

Dana Image copyright @NaijaFlyingDr

Ile isẹ ọkọ-ofurufu kan ni Naijiria ti dẹbi ilẹkun baalu rẹ t'o ṣi nigba ti ọkọ naa balẹ ru ero kan.

Ileesẹ ọkọ ofuurufu Dana sọ wipe ''o ṣoro ki ilẹkun baalu ṣi silẹ funrarẹ ti kii ba se wi pe ero kan lo gbiyanju ati ṣii.'

Lati igba ti isẹlẹ naa ti sẹlẹ ni orọ naa ti gbalẹ ni ori ẹrọ ayelujara Twitter nibi ti awọn eniyan ti n sọ wipe aibikita lo sokunfa iṣẹlẹ naa.

Baalu naa gbera lati Eko lọ si olu ilu Naijiria, Abuja, nibi ti ilẹkun baalu naa ti jabọ nigba ti o balẹ.

Sugbọn agbẹnusọ ileesẹ Dana sọ wi pe , "Ko si bi wọn yoo ti sọ wipe ilẹkun baalu naa n'mi nitori wi pẹ atẹgun kankan ko wọ inu baalu naa."

Ileesẹ naa se afikun wi pe awọn onimọ-ẹrọ ati ajọ to n se amojuto lilọ-bibọ awọn ọkọ-ofuurufu ni Naijiria se ayẹwo fini-fini lori baalu naa ki o to o gbera, wọn ko si ri ami iyọnu kan-kan.

Agbẹnusọ ileesẹ naa tun sọ wi pe : "Baalu naa gbera leyin isẹju mẹjọ si igba ti o yẹ ko gbera nitori wi pe a fi asiko diẹ kọ awọn ero nipa bi wọn yoo ti daabo bo arawọn nigba ti baalu ban mi ti-ti."