Afegbua jẹ'pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS

Kassim Afegbua, agbẹnusọ ajagunfẹ́yinti Ibrahim Babangida Image copyright Kassim Afegbua
Àkọlé àwòrán Afegbua ni ileesẹ ọlọpa n tẹ ẹtọ oun loju mọlẹ

Kassim Afẹgbua ti o jẹ agbẹnusọ fun aarẹ orilede Naijiria nigbakan ri, Ibrahim Babangida ti de si ile-iṣẹ ti Igbimọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati dahun si ipe wọn lori atẹjade ti o fi lede lọsẹ ti o kọja.

Afẹgbua de s'ibẹ ni bi agogo kan ọsan oni.

Ọgbẹni Afẹgbua gba ipe lati ọdọ SSS ni ọjọbọ, o si pinnu lati yọ'ju si igbimọ naa loni.

Ọlọpa tọrọ aforiji lọwọ Afegbua

Ọgbẹni Afegbua lọ s'ibẹ pẹlu awọn amofin mẹjọ lẹyin ti o ti fi ẹsun kan ileesẹ ọlọpa pẹlu ile ẹjọ giga ti ilu Abuja.

Afegbua, agbẹnusọ fun aarẹ orilede Naijiria nigbakan ri, Ibrahim Babangida, ṣe atẹjade ọrọ kan nipa eto isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari lọsẹ ti o kọja ti eyi si da awuyewuye si'lẹ.