Osinbajo: Idasilẹ ọlọpa agbegbe yoo dẹkun ikọlu lorilẹede Naijiria

Igbakeji aarẹ Ọsinbajo Image copyright @ProfOsinbajo
Àkọlé àwòrán Igbakeji aarẹ Ọsinbajo ni ọrọ abo ti di agbatẹru gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo ti yanana rẹ wipe bi orilẹede Naijiria ba fẹ bọ kuro lọwọ wahala ikọlu ati ipaniyan to n fojojumọ waye, idasilẹ ọlọpa agbegbe ati tipinlẹ di ọranyan.

Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo sọ ọrọ yii nibi apero lori eto aabo n'ilu Abuja.

Awọn asofin apapọ n ni ifọwọsowọpọ pẹlu ẹka isakoso gbe apero ọrọ aabo kalẹ latari ipenija to n de ba ibagbepọ alaafia ati aabo ẹmi ati dukia kaakiri awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Saraki ni ọranyan ni iforikori, ifikuluku lori ọna abayọ kuro ninu ikọlu ati ipaniyan lorilẹede Naijiria

Ninu ọrọ rẹ, Igbakeji aarẹ Yẹmi Osinbajọ ni Ọkọọkan ọmọ orilẹede Naijiria lo lẹtọ si aabo to peye fun ẹmi ati duki wọn.

O ni atunto ni lati de ba agbekalẹ isẹ ọlọpa lorilẹede Naijiria ki wọn si sọ iye ọlọpa orilẹede yii di ilẹpo mẹta iye rẹ bayii fun amojuto aabo tẹru-tọmọ.

Ohun ti Igbakeji aarẹ Yẹmi Ọsinbajo sọ

"Fun ijafafa ẹka eto abo, a ni lati tubọ sisẹ awọn nkan wọnyii:

Eni- A nilo lati se agbeyẹwo awọn nkan bii aato ileesẹ ọlọpa nipa sise alekun iye ọlọpa orilẹede yii ni ilọpo mẹta iye rẹ bayii fun amojuto aabo tẹru-tọmọ.

Eji- Idasilẹ ọlọpa agbegbe ati ipinlẹ lati dẹkun ọwọja ohun ija oloro to n wọle si orilẹede yii, lati wa ojuutu si lati mu nkan rọsọmu lẹka eto abo lorilẹede Naijiria.

Ẹta- Igbọraẹniye ni lati wa larin awọn ipinlẹ to fi ẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ara wọn laarin aala kan naa."

Nigba to n gb'osuba fun awọn osisẹ alaabo ati ileesẹ ọmọogun fun isẹ takuntakun ti wọn nse lai naani ọda owo awo olokun to wa nilẹ lorilẹede yii, Ọjọgbọn Ọsinbajo sekilọ wipe ati ijọba ati gbogbo lẹnilọrọ lo gbọdọ gbiyanju lati rii wipe aigbọraẹniye yii ko burẹkẹ di ija ẹlẹyamẹya tabi ẹlẹsinmẹsin. Ojuse awọn olori ẹka ẹsin ati oselu gbogbo lorilẹede Naijiria.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Awọn ipenija to n ba ibagbepọ alaafia ati eto abo orilẹede Naijiria finra lo sokunfa apero ọrọ abo ti awọn asofin se nilu Abuja

Ohun ti Aarẹ ileegbimọ asofin orilẹede Naijiria, Bukọla Saraki sọ.

Ninu ọrọ tirẹ nibi apero naa, Aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki ni afi ẹni to ba fẹ pamọ si ẹyin ika kan soso ni yoo sọ wipe ohun to n sẹlẹ lorilẹede Naijiria lọwọ yii ko fẹ apero pẹlu bi awọn ileto to ti figbakanri dawọ idunnu ọrẹ s'ọrẹ se di eyi ti wọn n gbe ohun ija oloro fi ba ara wọn ja.

"A wa nibi loni nitori awọn ipenija to n ba ibagbepọ alaafia ati eto abo orilẹede Naijiria finra. O di ọranyan bayii lati fi orikori, fikuluku ki a si jumọ pete pero lori ọna abayọ kuro ninu wahala yii.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Ireti awọn eeyan ni pe ki apero ọrọ abo to n lọ lọwọ o so eso rere pẹlu gulegule ikọlu ati ipaniyan to n waye lorilẹede Naijiria

Bi iwa ikọlu ati ipaniyan se wa di tọrọ-fọnkale kaakiri orilẹede Naijiria bayii n se afihan aisi abo fun ẹmi ati dukia awọn eeyan lorilẹede lo ji wa kuro ninu orun aibikita ti gbogbo wa n sun tẹlẹ."

Ikọlu ati ipaniyan laarin awọn darandaran fulani ati awọn agbẹ olohun ọsin to ti di kale-n-kako lawọn ipinlẹ bii Benue, Taraba, Adamawa ati oniruru ijinigbe kaakiri kun ara ohun to sokunfa bii awọn asofin apapọ se gbe apero ọrọ abo silẹ lati jiroro sna abayọ.