Addo: Atunto n bọ ni ileesẹ ọlọpa Ghana laipẹ

Aarẹ orilẹede Ghana, Akufo Addo Image copyright Getty images/ISSOUF SANOGO
Àkọlé àwòrán Idagbasoke ọrọ aje orilẹede Ghana ti n mu ireti idagbasoke ọtun ba awọn eeyan ibẹ

Aarẹ orilẹede Ghana, Akufo Addo ti pinnu atunto ileesẹ ọlọpa gẹgẹbii ara ipinnu tuntun lati wọ'ya ija pẹlu iwa ọdaran lorilẹede ọhun.

Lasiko to fi n ba awọn eeyan orilẹede Ghana sọrọ ni Aarẹ Akufo Addo ti sọ eyi di mimọ.

Ọkan-o-jọkan isẹlẹ idigunjale, ifipa se'wọde ati ipaniyan to lọwọ awọn darandaran lọwọ lo ti n ranju mọọ mọeto abo lorilẹede Ghana.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idagbasoke to n de ba ọrọ aje Ghana ko tii han lara awọn ọ̀mọ orilẹede naa

Saaju, owo to to ọgọsan miliọnu dọla owo ilẹ Amẹrika ni ijọba ti kọkọ gbe kalẹ lorilẹede naa lati kin awọn ọlọpa lẹyin ninu isẹ gbigbogunti iwa ọdaran eleyi ti aarẹ orilẹede Gahana ni yoo tubọ se miranwọ fun eto abo to munadoko.

Aarẹ orilẹede Ghana ni igbesẹ to loorin ti n lọ lati wa ojuutu ẹlẹkunjẹkun si iwa ipa ati ikọlu awọn darandaran nibẹ

Bakannaa ni aarẹ orilẹede Ghana tun kede wipe ayipada ti n de ba ọrọ aje oril€de naa pẹlu afikun pe ni opin ọdun yii ni owo iranwọ ti orilẹede naa gba lọwọ ajọ isuna agbaye, IMF yoo pari ti o si ni igbesẹ to yanranti ti wa nikalẹ lati rii daju wipe orilẹede naa ko maa sa tọ awọn orilẹede ati ajọ okeere mọ fun iranwọ.

Image copyright AFP Contributor
Àkọlé àwòrán Aisi isẹ fun awọn ọdọ kun ara ipenija to n ba orilẹede Ghana finra

Banki agbaye ti salaye saaju asiko yii wipe idagbasoke oniida mẹjọ ninu ọgọrun ni yoo de ba ọrọ aje orilẹede Ghana eyi ti yoo sun soke gẹgẹbii ọrọ aje to n dagbasoke ju lọ lagbaye.

Amọsa o, ipa ayipda ati idagbasoke ọrọ aje yii ko tii maa fi ara han ninu igbe aye awọn ọmọ orilẹede Ghana.

Bẹẹni Aarẹ Addo ko mu ẹnu lọ si ori ọrọ nipa ẹkunwo epo bẹntiroolu lorilẹede naa eleyi ti awọn ọmọ orilẹede naa kan tori rẹ se iwọde ni ọjọọru.