Buhari ni idasilẹ papa ijẹko maluu ko wa lati mu ẹya kan sin

Buhari ati awọn bisọọbu ijọ aguda Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kirisitẹni, Naijiria n lewaju ipe fun igbesẹ to yẹ lori ipaniyan awọn darandaran fulani to n waye kaakiri orilẹede Naijiria

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni ko si ootọ ninu ọrọ to n kaakiri wipe ọgbọn ati yẹ ọna fun ẹya kan lati jẹ gaba lori ẹya miran ni aba idasilẹ papa ijẹko ti ijọba n gbimọran rẹ lati fi dẹkun wahala laarin awọn darandaran fulani ati agbẹ olohun ọsin lorilẹede Naijiria.

Lati igba ti iroyin nipa aba idasilẹ papa ijẹko ti lu sita fun aye gbọ ni o ti da ọpọlọpọ awuyewuye ati gbọyisọyi silẹ.

Bi awọn igun kan lorilẹede Naijiria se n pariwo awọn faramọ ni awọn igun miran n ke gbajare wipe ko soun to jọ.

Image copyright Getty Images/PIUS UTOMI EKPEI
Àkọlé àwòrán Ọpọ lo n fi ẹsun kan Buhari wipe o joko tẹtẹrẹ lai tara si ọrọ ẹmi to n fi ojojumọ sofo lori ikọlu awọn daranadaran

Sugbọn aarẹ Buhari to n gbalejo awọn Bisọọbu ijọ aguda lorilẹede Naijiria nilu Abuja salaye ọrọ wipe, irẹ ati ahesọ lasan ni iroyin pe eredi idasilẹ awọn papa ijẹko ti ijọba n gbimọran rẹ ni lati mu awọn ẹya kan sin.

Ipaniyan Benue: Buhari sepade pẹlu awọn t'ọrọ kan

Buhari se'pade pẹlu olori ọmọ ogun, alakaso eto aabo

"Ibeere ati ahesọ ọrọ irọ ti n lọ kiri lori ojutu ti ijọba gbe kalẹ fun isoro ẹran dida. Ẹ jẹ ki n se afọmọ ọrọ yii fun yin wipe lẹyin ọpọlọpọ ifikuluku pẹlu awọn to nimọ ni igbesẹ yii jẹyọ. Ko wa lati mu ẹya kankan sin lorilẹede yii."

Bakanna ni aarẹ orilẹede Naijiria tun sọọ di mimọ wi pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn kọlọransi kan lori ikọlu ati ipaniyan to waye lawọn ipinlẹ bii Benue, Adamawa, Taraba ati Zamfara.

Buhari ni gbogbo awọn ti ọwọ ofin ba yii naa ni yoo fi oju wina ofin.

"Lootọ awọn isẹlẹ ipaniyan to n waye kaakiri awọn ipinlẹ Benue, Adamawa, Taraba ati Zamfara jẹ ohun to ba eniyan ninu jẹ pupọ sugbọn gbogbo ipa ati agbara ni mo n sa lati rii pe idajọ ododo waye pẹlu aabo to peye fun ẹmi ati dukia araalu."

Image copyright Getty Images/PIUS UTOMI EKPEI
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn kọlọransi kan lori ikọlu ati ipaniyan to waye lawọn ipinlẹ kan.

Pẹlu bi ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kirisitẹni, CAN lorilẹede Naijiria ti se lewaju ọkan-o-jọkan ipe fun igbesẹ to yẹ lori ipaniyan awọn darandaran fulani to n waye kaakiri orilẹede Naijiria, ipade naa fun Aarẹ Buhari ni anfani lati ohun ti isejọba rẹ n se lati wa egbo dẹkun si wahala agbẹ ati darandaran to n fi ojojumọ peleke sii kaakiri orilẹede naa.

Buhari ko sai sọrọ lori bi awọn eeyan kan lorilẹede Naijiria se n fi ẹsun kan an wipe n se lo joko kalẹ sojukan lai tara si ọrọ ẹmi to n fi ojojumọ sofo lori ikọlu awọn daranadaran pẹlu alaye wipe ko si ootọ ninu ifisun yii atipe gbogbo igbesẹ to tọna ni ibamu pẹlu ofin nijọba n gbe lori aabo ati alaafia lorilẹede Naijiria.