Ikọlu darandaran: Fayọṣe ṣe abẹwo si Ortom ni Benue

Aworan Fayose ati Ortom

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Àkọlé àwòrán,

Fayọṣe ni gbọin gbọin loun wa lẹyin ofin ipinlẹ Benue to fopin si fifẹran jẹ

Gomina Ayọdele Fayọṣe ipinlẹ Ekiti ti ṣe abẹwo si akẹgbẹ rẹ Gomina Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue.

Nigba ti o wa ni Benue, Gomina Fayọṣe kẹdun pẹlu awọn ara ipinlẹ naa lori ipaniyan to gbalẹ nibẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo BBC pẹlu Lere Olayinka ti o jẹ agbẹnusọ fun Gomina Fayọṣe, o ni Fayọṣe t'ẹnumọ pataki igbepọ lalafia laarin awọn ọmọ orilẹede yi.

O tẹsiwaju pẹ digbi ni oun wa lẹyin ofin ijọba ipinlẹ Benue ti o lodi si fifẹran jẹ kaakiri lalai bikita.

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Àkọlé àwòrán,

Wahala ikọlu ati ipaniyan n fojojumọ peleke nipinle Benue

Lasiko abẹwo naa, Gomina Fayọṣe yọju si aye ti wọn sin awọn eniyan mẹtalelaadọrin ti o padanu ẹmi wọn nigba ti awọn afurasi darandaran se ikọlu pẹlu wọn.

O ni ''O di dandan lati wa wọrọkọ fi ṣ'ada lori idasilẹ ọlọọpa agbegbe. Ka ni ọlọpaa ibile wa ni, gbogbo nkan yi o ni maa ṣẹlẹ''

O pẹ fun ikọwefiposilẹ ọga ọlọpa ẹni to ni o ni ipa buruku lori Aarẹ Buhari pẹlu bi o ti sẹ sọ ara rẹ di agbẹnuso ati olugbẹlẹyin fun awọn darandaran''

Fayọṣe ni Gomina ẹlẹkeji ti yoo lọ si ipinlẹ Benue.

Ṣaaju ni Gomina Wike ti ipinlẹ Rivers ti se abẹwo si Benue ti iroyin si sọ wi pe o kede iranwọ igba miliọnu naira fun ipinlẹ naa.