Lẹkki: Araalu gbanajẹ lori afikun owo ibode

Ifẹhonuhan Lẹkki lori ẹkun owo irinnọ
Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ fẹhonuhan lagbegbe eti ọsa lori ifinku

Ọpọlọpọ eniyan tu s'ita lagbegbe Lẹkki nibilẹ eti ọsa lati fẹhonuhan lori afinku owo irinna ẹnu ibode (Toll gate) ninpinlẹ Eko lọjọ ẹti.

Akọroyin BBC, Adedayo Okedare ti o jade pẹlu awọn ogunlọgọ eniyan ti o tu jade fẹhonuhan sọ wipe inu awọn ko dun si afikun ti ijọba se fun owo irinna yii ati wipe o jẹ ipalara fun awọn olugbe adugbo lekki ati Ajah ti wọn maa nlo awọn ibusọ wọn yii lojoojumọ.

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ eko se afikun owo irinnọ ẹnu ibode ni agbegbe lekki lati ọjọ kni osu keji ọdun yi

Adari awọn afẹhonuhan, Dotun Hassan salaye wipe o jẹ ohun ibanujẹ fun awọn olugbe lori ijọba awarawa nipinlẹ eko fun ijọba ati igbimọ ti o n risi eto irinna jadejado ipinlẹ yii lati fi kun owo irinna.

Ọgbẹni Hassan sọ siwaju wipe o jẹ iwa ti ko bojumu fun ijọba ati wipe o n fa irora fun awọn eniyan.

Àkọlé fídíò,

Ifẹhonuhan Lẹkki lori ẹkun owo irinnọ

Nigbati akọroyin wa se abẹwo si ile iṣẹ ti o n se amojuto ati akoso eto irinna, ko si ẹni ti o dahun ibeere akọroyin wa.