Kassim Afegbua yoo pada s'ọdọ ajọ DSS loni

Kassim Afegbua, agbẹnusọ ajagunfẹ́yinti Ibrahim Babangida

Oríṣun àwòrán, Kassim Afegbua

Àkọlé àwòrán,

Afegbua ni ileesẹ ọlọpa n tẹ ẹtọ oun loju mọlẹ

Kassim Afegbua to jẹ agbẹnusọ fun aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ibrahim Babangida yoo pada si ọfiisi ajọ ti o n ri si ọrọ aabo ọtẹlẹmuyẹ ilu, DSS lọjọ ẹti.

Olori ajo DSS, ọgbẹni Lawal Daura ti o pe ọgbẹni Afẹgbua fun ifọrọwerọ ko si n'ile lati ri i lọjọbọ, lofi wa fi ipade naa si agogo mọkanla loni.

Ajọ awọn ọlọpa idakonko naa wipe olori ajọ naa lọ fun ipade pajawiri ni ko se le e ri ọgbẹni Afẹgbua lasiko ti wọn jọ fi adehun si wipe ki o wa ro t'ẹnu rẹ.

Idi ti awọn ọlọpa ati ajọ DSS fi kọ'we ran sẹ pe ọgbẹni Afẹgbua ko ṣẹyin lẹta ti wọn fẹsun kan an wipe o buwọlu fun aarẹ tẹlẹri naa, Ibrahim Babangida, eyi ti awọn eleto aabo sọ wipe o le da rudurudu s'ilẹ.