Aarẹ Ọna Kakanfo kilọ fun awọn darandaran fulani

Aarẹ Gani Adams
Àkọlé àwòrán,

Awọn darandaran ti sekupa ogunlọgọ eniyan lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria

Aarẹ Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba, Otunba Gani Adams ti kilọ fun awọn fulani darandaran wipe ilẹ Yoruba ko ni i faaye gba pipa awọn eniyan bi adiyẹ nigba kugba.

Ọtunba Adams s'ọrọ yii nigba ti o n fi ẹhonu rẹ han lori bi awọn Fulani darandaran se n sekupa awọn eniyan ati bi wọn se fẹsun kan darandaran kan wipe ohun lo sekupa olori awọn eleto aabo ni ipinlẹ Ọyọ.

Ikilọ naa wa ninu atẹjade ti oludamọran pataki fun Aarẹ Ona Kakanfo, Kẹhinde Aderẹmi fi ranṣẹ s'awọn oniroyin, nibi ti o ti safiwe awọn darandaran to n paniyan gẹgẹ bii mujẹmujẹ.

Gani adams ti o sapẹẹrẹ bi awọn Fulani darandaran se jo oko oloye Olu Falae ti o jẹ ọkan gboogi ninu awọn ọjọgbọn nilẹ Yoruba, wa a fikun un wipe awọn ọmọ Yoruba ni ohun gbogbo ti wọn nilo lati fi daabo bo ara wọn, ati wipe awọn ko nii f'aaye gba iru rẹ mọ.

Aarẹ Ona Kakanfo ti ilẹ Yoruba naa wa parọwa si aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari lati rii daju wipe ọwọ sikun ọlọpa tẹ awọn apaniyan wọnyi.