NBC kilọ fun awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ lori isọrọ odi

Mallam Ishaq Modibbo Kawu, Oludari agba NBC

Oríṣun àwòrán, @nbcgovng

Àkọlé àwòrán,

Ọdun 2019 ni idibo gbogboogbo yoo waye ni Naijiria

Ajọ ti o n risi iṣakoso igbohunsafẹfẹ lorilẹede Naijiria, (NBC) ti ka awọn ofin ati aigbọdọmaṣe to wa fun awọn ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ lori ipolongo awọn ẹgbẹ oselu ati isọrọ odi lori afẹfẹ.

Adari ajọ naa, Mallam Ishaq Modibbo Kawu sọ wi pe ile-iṣẹ igbohunsafẹfẹ ti o ba lodi si awọn ofin to de igbohunsafẹfẹ, yoo f'oju wina ofin ilẹ Naijiria.

Kawu sọ pe ko tọ fun ile-isẹ igbohunsafẹfẹ lati maa ka lẹta ipolonlogo ẹgbẹ oselu nigba ti akoko idibo ko tii sunmọ'le. O sọ eyi nigba to n ba awọn akọroyin s'ọrọ ni ipinlẹ Plateau lori eto lati kuro ni ọnọ igbohunsafẹfẹ ti atijọ wa si ti igbalode (DSO).

Adari ajọ naa sọ wipe ni ipari osu kẹrin ọdun 2018, lawọn yoo palẹmọ gbogbo igbohunsafẹfẹ lọnọ atijọ, to si kilọ fun awọn ile-iṣẹ igbohunsafẹfẹ lati sapa wọn lati gbe iṣakoso orilẹede Naijiria lọnọ tiwantiwa larugẹ.

Lori isọrọ odi, Kawu kilọ f'awọn ile-isẹ igbohunsafẹfẹ lati sọ'ra lati maa gbe ọrọ odi s'ori afẹfẹ, eleyi ti o sọ wipe o le e da ija silẹ lorilẹede Naijiria.

Ọdun 2019 ni idibo gbogboogbo yoo waye ni Naijiria.