Sisọ ede Yoruba di ofin nipinlẹ Eko

Amọbde f'agbara fun ede Yoruba

Oríṣun àwòrán, @AkinwunmiAmbode

Gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambọde ti buwọlu ofin to f'agbara fun ede Yoruba gẹgẹbi ede t'awọn ara ilu yoo maa sọ nibi ise ati fun karakata.

Ambọde ninu atẹjade fun awọn oniroyin buwọlu ofin meje ninu rẹ ni ofin to gbe ede Yoruba larugẹ, idaabobo ina mọnamọna, lilo ile-iwe ẹkọ yiya owo, imọ nipa aisan jẹjẹrẹ ati fifi agbara fun ile-ẹjọ to n risi ọrọ lọkọlaya.

Kọmisọna fun ọrọ iroyin ni ipinlẹ Eko, ọgbẹni Kẹhinde Bamigbetan nigba to n sọrọ lori ofin tuntun to de ede Yoruba naa, sọ wi pe ohun idunnu ni o jẹ fun awọn wipe ede Yoruba ti di gbajugbaja lawujọ ipinlẹ Eko.

Bamigbetan sọ pe ofin naa f'aṣẹ fun awọn ile-ẹkọ giga ni ilu Eko lati gba kirẹdiiti ni ede Yoruba gẹgẹ bi ọkan lara kirẹdiiti marun ti wọn nilo lati wọ ile iwe giga.

Kọmisọnna naa wa fikun wipe ijọba ipinlẹ Eko mu ede Yoruba lọkunkundun ati wipe ohun iyi lo jẹ fun wọn lati gbe ede Yoruba larugẹ.