Benue: ‘Operation Cat Race’ ko lee yanju ikọlu darandaran

Fulani darandaran
Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ ẹmi ti sọnu nitori ija Fulani darandarn ati agbẹ ni Naijiria

Laipẹ yi ni ileesẹ ologun Naijiria ṣe ifilọlẹ ikọ ọmọ ogun kan to pe ni "Operation Cat Race" lati wa ojutu si wahala to n waye laarin awọn agbẹ ati daran-daran lawọn ipinlẹ kan l'orilẹede Naijiria.

Lori igbesẹ yii, awọn olugbe lati diẹ lara awọn ipinlẹ ti ọrọ yi kan si ti fi ero wọn han.

Alukoro fun ẹgbẹ to n risi idagbasoke ilu Numana jakejado agbaye, John Bature Mazo ni, awọn f'aramọ igbesẹ ileesẹ ologun lori idasilẹ eto naa ti wọn pe ni 'Operation Cat Race'.

Ilu Numana jẹ ọkan lara awọn ilu to ti lugbadi ikọlu daran-daran lẹkun Guusu Kaduna.

O ni "igbagbọ wa ni wipe igbesẹ naa yoo mu opin de ba ija to n waye ni gbogbo igba laarin awọn darandaran ati agbẹ lawọn ipinlẹ kan l'orileede yi.

"A nilo alaafia ni Guusu Kaduna."

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ẹmi lo ti bọ, ti aimọye dukai si sofo latọwọ awọn Fulani darandaran

Bakannna ni Ọgbẹni Usman lati ipinlẹ Nasarawa ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ ni "emi naa fi ara mọ igbesẹ yi.

"Igbesẹ to daraju lọ lati fi opin si ija laarin awọn daran-daran ati agbẹ niyi.

"A le sun asun f'orile osuka bayii. Ireti wa si ni wipe gbogbo rẹ yoo wa s'opin."

Onwoye awujọ kan ni amulo ọmọogun kọ lọrọ naa kan

Sugbọn ninu ọrọ ti onimọ nipa eto aabo, ajagunfẹyinti Ayo Olaniyan, o ni alaafia lo se pataki julọ ni awujọ ọmọniyan. "

"Lootọ ni awọn kan sọ wipe, igbesẹ yii pẹ ko to waye, ta ba ni ka wo iye ẹmi to ti sọnu, ṣugbọn ireti wa ni wipe afojusun igbesẹ naa yoo wa si imuṣẹ. Bẹẹ si ni nkan to le mu opin ba wahala yii kii se amulo awọn ọmọ ologun, bi ko se wiwa ojutu si awọn nkan to n fa wahala yii gan, bi aisi ilẹ fun awọn daran-daran lati fi ẹran jẹko ati ayipada oju ọjọ nipato."

"Igbesẹ ileesẹ ologun ko le yanju awọn ọrọ wọn yi, o yẹ ka gbe igbesẹ to yẹ lati hu wahala yi tigbongbo-tigbongbo ni.

"Lara ọrọ to yẹ ki ijọba tun mojuto ni lati sise iwadi orisun ibi ti awọn daran-daran ti n ri awọn nkan ijagun ti wọn n gbe kiri.