Edo: Ẹran dida ati ibọn gbigbe deewọ

Darandaran ati maalu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ijoba ipinlẹ Ekiti ati Kogi ti fofin de didaranjẹ saaju ki ipinlẹ Edo to gbe igbesẹ yii

Ijọba ipinle Edo ti fofin de asa dida ẹran lalẹ ati gbigbe ibọn rin laarin awọn darandaran.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ naa, Crusoe Osagie, fisita ni ọjọbọ sọ wipẹ, ijoba ipinle naa ti yan igbimọ ẹlẹni meje nijọba ibilẹ kọọkan nipinlẹ Edo lati dẹkun ikọlu awọn agbẹ ati darandaran.

Lara awọn ọmọ igbimọ naa ni alaga ijọba ibilẹ kọọkan, ọga ọlọpa ni agọ ọlọpa gbogbo to wa nijọba ibilẹ ọhun, awọn asoju ileesẹ ọtelemuye ati awọn ara ilu mẹrin-mẹrin nijọba ibilẹ kọọkan.

Ipinlẹ Edo si tun ti fofin de igbesẹ kawọn Ọdẹ ibilẹ lati ipinlẹ mii maa se ọdẹ wa si ipinlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Edo pinnu lati gbe awon igbesẹ wonyi lẹyin igba ti gomina Godwin Obaseki se ipade pẹlu awọn asoju Hausa ati Fulani lati ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa ni ipinlẹ naa.

Gomina Ọbaseki sọ wipe ijọba yoo gba orukọ awon asaaju Fulani silẹ ni gbogbo agbegbe to wa nipinlẹ naa ati wipe, awọn Seriki Fulani naa ni wọn yoo maa ba gbogbo darandaran sọrọ l'agbegbe wọn.

Gomina Godwin Obaseki se afikun rẹ wipe, irufẹ igbimọ yi, ti oun yoo lewaju rẹ nipinlẹ naa, ni ọga ọlọpa ipinlẹ Edo, oludari ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ naa, olori ileesẹ ologun ati awọn eeyan lati ẹkun idibo mẹta to wa nipinlẹ Edo yoo jẹ ọmọ igbimọ.

Saaju ki ipinlẹ Edo si to gbe igbesẹ yi, ni ipinlẹ Ekiti ati ipinlẹ Benue ti fofin de asa ẹran dida ninu igbo ati laarin igboro ilu.

Sugbọn olori ẹgbẹ kan to jẹ tawọn darandaran Fulani (Gan Allah Fulani Development Association), Alhaji Saleh Bayeri, sọ wipe ko yẹ ki ipinlẹ Edo se agbekalẹ ofin to l'odi si ẹran dida lalẹ nitori awọn Fulani kii daranjẹ lalẹ

O s'afikun wipe didaranjẹ lalẹ ni ewu fun awọn maalu ati darandaran nitori ikọlu eranko bi ikoko ati ejo.

Alhaji Bayeri sọ wipe gbogbo Fulani to ba n daran lalẹ, afurasi ọdaran niru wọn.