Cameroun: Awọn sọja tu mi sihoho-obinrin to satipo

Oju awọn eeyan un guusu Cameroun nri mabo lọwọ awọn ologun orilẹede naa.
Awọn ọsisẹ ajọ to nse iranwọ f'awọn eniti ajalu deba ni Naijiria so wipe awọn eeyan to sa asala fun ẹmi wọn to le ni egberun lọna ogoji ni wọn yaa wọ orilẹede Naijiria lati orilẹede Cameroun to mule ti Naijiria.
O ni iye awọn eniyan naa npọsi, ti ẹka ajọ to nseto iranwọ labẹ ajọ isọkan agbaye sọ wipe ewu pọ fun awọn obirin ati ọmọ wẹwẹ laarin awọn eeyan to wa se atipo naa.
Awọn atipo naa nsa kuro ni guusu Cameroon nibi ti awọn soja tin gbogunti awọn ti wọn njija ọminira, lati da orilẹede ti wọn pe ni Ambazonia silẹ lawọn agbegbe ton sọ ede gẹẹsi nitọri ohun ti wọn pe ni "isẹlu to fi sọdọ awọn eeyan to wa lagbegbe to nsọ ede Faranse".
Wọn sọ wipe awọn to wa ni agbegbe ti wọn tin sọ edẹ Faranse nfun awọn ni wahala lati ri isẹ se ati nidi iwe kika, to fi mọ ipese eto ilẹra, iselu ati didi ipo asaaju mu.
Ọpọ awọn atipo naa ngbe lawọn abule to wa lẹnu alaa Naijiria ati Cameroun nipinlẹ Cross Rivers, lẹkun guusu Naijiria, tawọn mii naa si wa nipinlẹ Benue, to wa ni ẹkun aarin gbun-gbun ariwa orilẹede yii.
Awọn atipo naa tiẹ salaye nipa iru lasigbo to n koju wọn.
'Mo fi ẹsẹ min rin ninu igbo fun ọjọ mejọ'
Ogunlọgọ awọn eeyan ni wọn padanu ile wọn ni agbegbe guusu Cameroon to gba ominira lọwọ eebo amunisin.
Gẹgẹ bi Ọgbeni Rene ti salaye fun ikọ iroyin BBC ,o ni oun, iyawo oun atawọn ọmọ fọ̀n ka, nigba tawọn soja Cameroon kolu abule wọn, ti wọn si se ibẹ sakasaka, bẹẹni wọn gbẹmi ọpọlọpọ eniyan
Iyaw ore ati awọn ọmọ re se alabapade iranwọ lati ọwọ awọn enikan ti wọn gbe wọn lori alupupu fun wakati gbọọrọ.
Ija ominira fun ẹkun guusu Cameroun lo sọ awọn eeyan yi di alainilelori
Sugbọn ọkunrin naa fi ẹsẹ re rin fun asiko to ju ọse kan lọ.
O so wipe, ni gbogbo igba naa, oun ko jẹ ounjẹ kankan to ju eso igi lọ atawọn nkan oko min tawọn eeyan pinj sẹba ọna.
O lọ tọ ọjọ meji ninu igbọ ko to ri ọna ẹsẹ kan tọ gba lọ sabule kan ti wọn pe nii Bashu nipinlẹ Cross River to wa ni Naijiria, ni ibi to ti ba awọn ẹbi re laarin ọpọ atipo.
Rene sọ wipe: ''An gbe ni abule wa l'alafia ki awọn soja Cameroon to ja wọ aarin wa. A kan bere sini gburo ibọn ni laarin iseju die, eyi lo mu ka bere sini sa asala lai mọ ibi ta nlọ."
O sọ wipe: "Awọn kan ninu wa lo to ọjọ mejọ ninu igbo. Titi di asiko yi awọn ebi mi kan nbe tin nkọ mọ ibi ti wọn wa.''
Ni bayi Rene, ọmọ odun mejilelogbon ati ebi rẹ ngbe nilu Ikom to wa ni ipinlẹ Cross River, eyi toto kilomita metadinlogbon si ẹnu aala ibode Naijiria ati Cameroon.
Rene fi ibi toti f'arapa han olukoroyin BBC
'Awọn Sọja tu mi sihoho'
Ọpọ ninu awọn atipo naa sọ wipe awọn soja orilẹede Cameroon fi ilọkulọ lọ awọn. Ogunlọgọ awọn obirin ni wọn sọ wipe awọn soja tu wọn sihoho, ti wọn si tun tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ..
Nguma, to to ẹni ọgbọn ọdun, sọ pe awọn soja orilẹede Cameroun bọ asọ lọrun oun ati awon obirin miran.
Nguma ni awọn soja orilẹede Cameroun se asemase pelu oun ati awon obirin miran.
Nguma sọ wipe ''wọn na wa , wọn si bo wa sihoho, lẹyin nan ni wọn ju wa si inu odo.''
Awọn atipo kan ti wọn nlọ lori okọ oju omi lo ran wọn lọwọ, ti wọn si gbe wọn wọ orilẹede Naijiria.
Nguma so wipe botilẹ jẹ wipe awọn sọja yi ko fi tipa ba oun lo pọ. amọ oun gbọ wipe wọn fi tipa ba awọn obirin miran lọpọ.
Ọpọ eeyan guusu Cameroun di atipo lorilẹede Naijiria
Agbenusọ ijọba orilẹede Cameroon Issa Tchiroma Bakary, sọ fun BBC wipe awọn soja naa kan ngbiyanju lati daabo bo iyi orilẹede naa lasan ni pelu fifi ẹse alafia rinlẹ l'agbegbe guusu Cameroon niibi ti awọn ajijagbara tin gbiyanju lati da orilẹede ti wọn pẹ ni Ambazonia siilẹ.