Wọn dibo ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Kano

Sama da jam'iyyu ashirin ne ke fafatawa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn ẹgbẹ oselu ti wọn kopa ninu ibo naa le ni ogun

Ni ọjọ abameta ni wọn digbo ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Kano to wa ni lẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

Pẹlu ijọba ibilẹ mẹ̀rinlelogogji, Ipinlẹ Kano lo ni ijọba ibilẹ to pọ ju lọ lorilẹede Naijiria.

Alakoso ajọ eleto idibo ipinlẹ naa , ọmọwe Garba Ibrahim Sheka salaye fun akoroyin BBC wipe awọn ẹgbẹ ọselu ti o n kopa ninu ibo naa le ni ogun.

Sugbọn awọn owoye sọ wipe ẹgbẹ APC ti ikangun gomina ipinlẹ naa Abdullahi Umar Ganduje ni yoo je gaba nibi ẹsiibo naa.

Amọsa, ẹgbẹ ọselu PDP to jẹ ọkan pataki laarin ẹgbẹ oselu alatako ni ipinlẹ naa ko ni kopa ninu idibo ọhun nitori, gẹgẹ bi ẹgbẹ oselu naa ti sọ, owo fọọmu ti wọn taa fun awọn oludije fun ipo gbogbo ninu idibo naa ti pọọ ju.

Alaga ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Kano, sẹnẹtọ Mas'ud El-Jibril Doguwa sọ fun BBC wipe "a o lọ si kotu to ga ju lọ lati ri wipe ẹtọwa tẹwa lọwọ", leyin igba ti kotu kekere ti kọ lati gbọ ẹjọ ti ẹgbẹ naa gbe tọ ile ẹjọ lọ.

Idibo ijọba ibilẹ naa n waye lasiko ti gomina Ganduje nja ija oselu pẹlu sẹnẹtọ Rabi'u Musa Kwankwaso, ẹni to tii lẹhin lati de ipo gomina ipinlẹ naa lọdun2015.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

PDP ti gbe ibo naa lọsi ile-ẹjọ