Boko Haram titu awọn olukọni mẹta Unifasiti Maiduguri silẹ

Ẹgbẹ Boko Haram ti fi adooloro kọlu Unifasiti Maiduguri ni ọpọigba lẹyin

Oríṣun àwòrán, .

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ Boko Haram ti fi adooloro kọlu Unifasiti Maiduguri ni ọpọigba lẹyin

Atẹjade naa sọ wipe ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria (DSS) lo fi irọyin itusilẹ awọn olukọni unifasiti Maiduguri to wa ni ipinlẹ Borno naa to aarẹ Muhammadu Buhari lẹti ni ọjọ abamẹta.

Bakannaa ẹgbẹ naa si tu awọn iyawo ọlọpa mẹwa to jigbe silẹ leyin igba ti ileese ọtẹlemuyẹ Naijiria ati Igbimọ ICRC ton sẹ iranwọ f'awaọn t'ajalu ba f'ọrọjomitoro ọrọ pẹlu Boko Haram naa .

Atẹjade naa sọ wipe aarẹ Muhammadu Buhari lo pasẹ pẹ ki ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria ko kansi Boko Haram naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbimọ ICRC lo se alarina ijiroro laarin ileese ọtẹlẹmuyẹ Naijiri ati ẹgbẹ Boko Haram naa.

Ọgbẹni Garba Shehu sọ wipe awọn eeyan mẹtala ti won tusilẹ naa wa lọwọ ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, ati wipe awọn ọmọogun Naijiria tin gbe awọn eniyan naa losi Abuja.

Shehu se afikun wipe inu aarẹ Buhari dun si itusilẹ yi, o si ke pe awọn ọmọogun Naijiria ati ileese DSS wipe ki wọn mura si se lati ri wipe awọn akekọbirin Chibok ti Boko Haram jigbe padawa si ile.