Ramaphosa ni ifiposilẹ Zuma gbọdo niyanju lọsan ọjọ ajé

Ramaphosa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ogbeni Rhamaphosa soro nibi ayeye ajodun ogorun ibi Nelson Mandela

Olori ẹgbe ọsẹẹlu ANC ni lọọto ni pẹ oju n kan awọn ọmọ ẹgbẹ lori bi wọn ko ti se ri ifiposile Aare Zuma yanju.

Cyril Ramaphosa ni oro naa 'gba suru lati yanju'

O sọ fun ogoro awọn ọmọ ẹgbe naa to pejọ sibi ayẹyẹ ọjọ ibi Aarẹ adulawo akọkọ lorilẹẹde South Africa, Nelson Mandela pe "A mo wipe o yẹ ki a yanju oro naa"

Wọn fi ẹsun ise owo ọba basubasu kan ogbẹni Zuma ti o ti wa ni ijọba fun ọdun mẹsan.

Ẹgbe osẹẹlu ANC ni awọn yoo se ipade lọjọ ajé lati fẹnu ko lori ibi ori nba ọrun re fun Aarẹ Zuma.

Akoroyin BBC fun Afrika Andrew Harding so wipe , o se se ki iko adari ẹgbẹ naa ni ki ọgbeni Zuma fipo sile.

Lọse to koja ni wọn fagile ipade igbimo apasẹ ẹgbẹ ANC kan to yẹ ko waye lẹyin ifikunlukun laarin ọgbẹni Zuma ati Ramaphosa ti o jẹ igbakeji aarẹ to si tun jẹ olori tuntun fun ẹgbẹ naa.